Afọ́jú gan-àn mọ bó sẹ ń lọ lẹ́ka ètò ẹ̀kọ́ nìpínlẹ̀ Kwara, nítorí pé kò sí òṣìṣẹ́ tó ń gba owó tó dín lẹ́gbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n náírà - Alaga NUT - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Tuesday, July 27, 2021

Afọ́jú gan-àn mọ bó sẹ ń lọ lẹ́ka ètò ẹ̀kọ́ nìpínlẹ̀ Kwara, nítorí pé kò sí òṣìṣẹ́ tó ń gba owó tó dín lẹ́gbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n náírà - Alaga NUT


Alaga ẹgbẹ awọn olukọ nipinlẹ Kwara, Kọmireedi Olu Adewara ti sọ pe ko si oṣiṣẹ, paapaa awọn olukọ to gba owo oṣu to kere si ọwọ oṣu tuntun ti ijọba apapọ orilẹ-ede Naijiria bu ọwọ lu, iyẹn ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira.

Adewara sọ pe arun oju ni, ki i ṣe arun to ba inu rara, nitori pe afọju gan an mọ pe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ naa ko fi ọrọ eto ẹkọ ṣere rara.
 
O ni bi afọju ka ba ri, o n fi eti gbọ awọn ipa ribiribi ti Gomina AbdulRazaq nko, bẹẹ lawọn aditi gan-an n foju ri awọn ohun to n ṣẹlẹ nipa idagbasoke eto ẹkọ.

Nigba to n sọ pe iyalẹnu nla ni iṣakoso ọdun meji gomina wọn jẹ, o rawọ ẹbẹ pe ki ijọba tubọ ba wọn ṣe agbeyẹwo owo ifẹyinti, igbega to wa nilẹ tẹlẹ ni TESCOM, ati awọn ohun to yẹ lati ṣe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI