Wòlíì Ayọdele tún ju àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìdìbò Gómìnà Anambra sílẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 27, 2021

Wòlíì Ayọdele tún ju àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìdìbò Gómìnà Anambra sílẹ̀


Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual Church, Primate Elijah Ayọdele ti sọ pe idibo to fẹẹ waye nipinlẹ Anambra ni yoo sọ awọn nnkan ti yoo ṣẹlẹ lọdun 2023.
 
Ninu asọtẹlẹ ti Wolii Ayọdele gbe jade lonii, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti tu pẹẹrẹpẹẹrẹ ọrọ, iyẹn asọtẹlẹ. Nibẹ lo si ti jẹ ko di mimọ pe Ọlọrun ti fi oriṣiriṣi nnkan ti yoo ṣẹlẹ lakooko idibo naa han oun, eyi to yẹ kawọn oludije tete dide ja lodi si.

O ni gbogbo ọna lẹgbẹ oṣelu to n lewaju lorilẹ-ede n wa lati yi ibo fun awọn ọmọ ẹgbẹ wọn, ki wọn le jawe olubori.

Siwaju si i ni Wolii Ayọdele tun sọ pe wọn maa fi ẹsun ọdaran kan awọn oludije lawọn ẹgbẹ oṣelu yooku, eyi ti yoo da wahala silẹ nipinlẹ naa.

"Inu mi bajẹ lori ohun ti Ọlọrun ṣẹṣẹ fi han mi, gbogbo awọn oludije ti wọn fẹẹ dije ni ẹgbẹ oṣelu to n lewaju maa fi ẹsun ọdaran kan, lati ori awọn to gbajumọ titi de ori awọn to ṣẹṣẹ n dide bọ. 

"Wọn fẹẹ ṣe akoba fun wọn, ki wọn si le fi ẹsun ọdaran kan wọn, lati le ri i pe awọn ọmọ ẹgbẹ wọn lo jawe olubori. Idibo Anambra ni yoo sọ bi ọpọ nnkan ṣe maa ri, mo ri yiyi ibo lọna igbalode ti awọn ẹgbẹ oṣelu to n lewaju ti pinnu re.

"Ibi yiyi ti n waye lorilẹ-ede Naijiri, ṣugbọn eyi yoo tun gba ọna ara yọ. Yoo le debi wi pe awọn ọmọ Anambra yoo kọju wahala sira wọn. Ẹ jẹ ki wọn kiyesara. Mo ri awọn alagbara mẹta ti wọn n pinnu lati yi ibo yii, ti wọn ba si fi ara wọn silẹ lati jẹ ki eto idibo naa lọ wọọrọwọ, ẹgbẹ APC ko le jawe olubori."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI