Alálùbáríkà ọmọ ni ẹ́, àsìkò rẹ n tù wá lára - Ẹmir Ilọrin gbé òṣùbà káre fun AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 22, 2021

Alálùbáríkà ọmọ ni ẹ́, àsìkò rẹ n tù wá lára - Ẹmir Ilọrin gbé òṣùbà káre fun AbdulRazaq


Beeyan ba wa nibi ti Ẹmir tilu Ilọrin, Alaaji Ibrahim Sulu-Gambari ti n gbe oṣuba kare fun Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq lonii, Ọjọbọ, Tọsidee, koda, bi omije ayọ ko ba jabọ loju iru ẹni bẹẹ, ori rẹ yoo wu, nitori pe idunnu nla lo jẹ fun wọn.
 
Alaaji Sulu-Gambari nibi abẹwo ọdun to ṣe lọ ki Gomina AbdulRazaq lo ti sọ pe iru eeyan tawọn ti n foju sọna fun lati ọjọ pipẹ ni, ati pe asiko tawọn nilo rẹ gidi lo gbegba oroke ninu idibo ọdun 2019.

O sọ siwaju pe igba ati asiko AbdulRazaq n tu awọn lara pupọ, ati pe awọn ko kabamọ wi pe oun lo n dari wọn.
 
“Ọlọlajulọ, o ti n ṣe daadaa. Jọwọ, tubọ tẹsiwaju lati maa ṣe daadaa, Ọlọrun yoo pin ẹ lere lẹkunrẹrẹ. A n fẹ alaafia nipinlẹ Kwara. A n fẹ alaafia niluu lọrin. A ko fẹ wahala.
 

“A ni lati maa ṣamulo iwa alaafia, ifẹ ati iṣọkan. Ọlọla julọ, ohun to dara lo n ṣe. Ọlórun yoo tubọ maa kun ẹ lọwọ. Ọlọrun yoo tubọ maa wa pẹlu ẹ, wa a si gbe titi lai ninu ifọkanbalẹ ọkan ati alaafia pipe.

“Inu mi tun dun lati wa nibi. Emi ṣi ni ọba to pẹ julọ lori itẹ, ninu iṣẹdalẹ ilu Ilọrin, ati kaakiri gbogbo ariwa orilẹ-ede yii. Orilẹ-ede ti ko ba si ni itan, a jẹ pe iru orilẹ-ede bẹẹ ti ku.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI