APC paroko buruku ranṣẹ si Lai Mohammed, wọn dawọn ọmọ ẹyin rẹ mọkanla duro ninu ẹgbẹ lojiji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 15, 2021

APC paroko buruku ranṣẹ si Lai Mohammed, wọn dawọn ọmọ ẹyin rẹ mọkanla duro ninu ẹgbẹ lojiji


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Kwara ti sọ pe ki minisita fọrọ aṣa, iroyin ati irin ajo afẹ lorile-ede yii, Alaaji Lai Mohammed lọ maa gbaradi lati gba idaduro ninu ẹgbẹ.

Ko din ni mọkanla awọn ọmọ ẹyin Lai Mohammed ti wọn da duro nipinlẹ naa, lori ẹsun agabagebe ninu ẹgbẹ, eyi ti wọn fi kan wọn.

Aroko nla ni eyi jẹ fun Lai Mohammed pẹlu bi wọn ṣe sọ pe koun naa lọ maa mura silẹ.

Ninu lẹta idaduro ti akọwe igbimọ apapọ ti yoo ṣakoso bi ipade gbogboogbo ẹgbẹ naa lapapọ, Sẹnetọ James Akpanudoedehe bu ọwọ lu, to si fi ranṣẹ si Ọnọrebu Abdullahi Samari Abubakar.

Awọn ti wọn da duro naa ni: Joseph Tsado, Bamidele Ogunbayọ, Issa Fulani, Imam Abdulkadir, Mọrufu Ọlaniyi Yusuf, Saludeen Lukman, Kerebu Fatai, Bọla Ajani, Nurudeen Fasasi, Salman Shehu Babatunde ati Abdullateef Ahmed Kolawole.

Ko si nnkan meji ti wọn loo fa a ki ẹgbẹ naa da wọn duro, bi ko ṣe bi wọn ṣe gbe alaga APC nipinlẹ naa, Ọnọrebu Abdullahi Samari Abubakar to court.

A gbọ pe gbogbo awọn ti wọn da duro yii ni wọn da wahala to pin ẹgbẹ naa si meji nipinlẹ Kwara silẹ, ni eyi tawọn kan ti tẹle Gomina AbdulRazaq, ti awọn mi in si tẹle Alaaji Lai Mohammed.

Wọn lawọn mọkanla lo gba kọọtu lọ lati fi ehonu wọn han lori bi wọn ṣe yọ Bashir Bọlarinwa gẹgẹ bi alaga igbimọ fidihẹ, ti wọn si fi Samari rọpo rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI