Awọn ọdọ olokoowo kekeeke bọ saye nla ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Wednesday, July 14, 2021

Awọn ọdọ olokoowo kekeeke bọ saye nla ni Kwara


Lonii, Ọjọru, Wẹsidee ni ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tun dẹrin pẹẹkẹ awọn ọdọ, paapaa awọn olokoowo kekeeke pẹlu pẹlu bo ṣe yọnda owo ti ko din ni miliọnu mẹta naira fun ẹnikọọkan lati ya fi bẹrẹ okoowo wọn.
 
Awọn ti ko din ni aadọsan, {170}, iyẹn awọn ọdọ ti ọjọ ori wọn bẹrẹ lati ọdun mejidinlogun si marundinlogoji ni wọn ti tẹwọ gba iwe sọwedowo wọn lọwọ ijọba.
 
A gbọ pe ijọba ipinlẹ naa lo sọ fawọn ọdọ lati kọwe ẹyawo naa, ki wọn si le jẹ anfaani lati duro, lai lọ maa tọrọ owo kiri mọ. Eyi lo jẹ kawọn eeyan bẹrẹ si i forukọsilẹ, ti wọn si ṣe agbeyẹwo gbogbo awọn to peregede patapata.
 
Owo tile diẹ ni ẹgbẹrun kan miliọnu {N101, 450, 000} naira la gbọ pe ijọba gbe kalẹ fawọn oloowo yii lati fi bẹrẹ iṣẹ, ti a si gbọ pe ileeṣẹ kereje marun-un ọtọọtọ, ti wọn dangajia ni wọn gba miliọnu mẹta-mẹta.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI