Ikunlẹ abiyamọ o! Tanka elepo tẹ mọto mẹwaa mọlẹ n'Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 14, 2021

Ikunlẹ abiyamọ o! Tanka elepo tẹ mọto mẹwaa mọlẹ n'Ibadan


Fun bi ọpọlọpọ wakati ni agbegbe Challenge to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ fi di gaga, to si fa sunkẹrẹ fakẹrẹ igbokegbodo ọkọ lagbegbe naa. 

Tankan elepo kan la gbọ pe ijanu rẹ ja sọnu lori ere asapajude, ni nnkan bi aago meje aarọ ana, Tusidee.

Asiko naa bọ si asiko ti wọn lawọn ọkọ n duro fun ina {Traffic Light}, ti wọn si ni mọto ti ko din ni mẹwaa ni tanka elepo naa kọlu, to si tẹ awọn mi in mọlẹ kọja atunṣe.

Orin ọpẹ ni wọn lawọn to wa lagbegbe naa mu sẹnu pẹlu bi ijamba naa ko ṣe mu ẹmi eeyan kankan lọ.

Ọjọ bi i meloo kan sẹyin ni tanka elepo kan naa tẹ eeyan ti ko din ni mẹwaa pa laaarin ọja niluu Ibadan kan naa yii.






No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI