Ayé ò! Wọ́n ni àjòjì obìnrin bímọ tuntun fún Ọ̀ọ̀ni Ifẹ̀, Ọba Ògúnwùsì - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 21, 2021

Ayé ò! Wọ́n ni àjòjì obìnrin bímọ tuntun fún Ọ̀ọ̀ni Ifẹ̀, Ọba Ògúnwùsì


Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i le fidi iroyin naa mulẹ daadaa lakooko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan, sibẹ iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ọkan lara awọn obinrin to wa laafin Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi ti bimọ tuntun lanti-lanti fun kabiyesi.

AWIKONKO gbọ pe obinrin to bimọ yii ko si lara awọn to n ṣiṣẹ ninu aafin Ọọni Ile-Ifẹ rara.

Ọkan lara awọn akọroyin ori ayelujara ti Instagiraamu, ti wọn pe ni Gistlover lo gbe iroyin naa sita laipẹ yii.

Gistlover ninu ọrọ to kọ sọ pe bonkẹlẹ ni Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi ṣe ọrọ naa, nitori pe Olori Naomi nikan lawọn eeyan mọ gẹgẹ bi iyawo rẹ.

Bakan naa, Gistlover ko sọ orukọ obinrin ọhun, bẹẹ si ni ko sọ iru eeyan to jẹ, ṣugbọn to jẹ ka mọ pe inu aafin lo n gbe pẹlu awọn obinrin mẹta kan tawọn naa n gbe pọ pẹlu Ọọni ati Olori Naomi.

Gbogbo akitiyan lati ba ọkan lara awọn to sunmọ aafin naa sọrọ lati fidi iroyin yii mulẹ lo ja si pabo titi dasiko ta a pari iroyin yii.

Ẹ ka nnkan Gistlover ko NIBI

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI