Ọ̀rọ̀ burúkú tòun tẹ̀rín-ín! Kabiyesi sálọ láàfin nítorí wàhálà àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 21, 2021

Ọ̀rọ̀ burúkú tòun tẹ̀rín-ín! Kabiyesi sálọ láàfin nítorí wàhálà àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn


Ko din ni eeyan meji ta a gbọ pe wọn ti dagbere faye nibi ikọlu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to waye lagbegbe Udianga Enem, ijọba ibilẹ Etim Ekpo, ipinlẹ Akwa-Ibom.

Ọjọ Aje, Mọnde la gbọ pe iṣẹlẹ ọhun waye, eyi ti wọn loo mu Ọba Josiah Udoekoriko, na papa bora kuro laaarin ilu latigba naa, lojuna lati daabo bo ẹmi rẹ.
 
Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn pe ni Iceland Confraternity ati Debam la gbọ pe wọn kọju ija sira wọn.

Wọn ni lati bi ọdun mẹrin sẹyin lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti n ba ara wọn fa wahala nijọba ibile Etim Ekpo ati Ukanafun, ti wọn si ti gbẹmi ọpọ awọn eeyan, paapaa awọn alaiṣẹ, koda, ti wọn ni dukia olowo iyebiye ti ba a lọ.

A tiẹ gbọ pe Gomina Udom Emmanuel tipinlẹ naa ti da si aawọ yii fun alaafia lati jọba lawọn agbegbe naa.

Olori ọmọ ẹgbẹ Iceland ti wọn pe ni Oto, lati ijọba ibilẹ Obon Ebot la gbọ pe o lewaju lọ sagbegbe Udianga Enem yii lati lọ gba awọn nnkan ti wọn lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Debam gba lagbegbe Obong Ntak.

Wọn ni erongba lati yanju aawọ to n ṣẹlẹ laaarin awọn ẹgbẹ mejeeji yii ni ẹgbẹ okunkun Debam, ti olori wọn Samuel Okonko, tọpọ awọn eeyan mọ si 'Angel Boy' gbe lọ, ṣugbọn ti wọn ni ipade naa yiwọ mọ wọn lọwọ.

Nibẹ la gbọ pe ẹnikan ti jade laye laaarin wọn, to si mu kawọn yooku ba ẹsẹ wọn sọrọ. Iro ibọn to n ro lakọlakọ la gbọ pe o mu kawọn eeyan salọ.

A gbọ pe awọn ara agbegbe naa ko le lọ fọrọ iṣẹlẹ yii to awọn ọlọpaa leti nigba ti kabiyesi to yẹ ko ṣaaju wọn ti na papa bora, ti wọn ko si ti i ri dasiko ta a pari iroyin yii.

Odiko Macdon, ẹni to jẹ agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, to si ni awọn ti bẹrẹ iwadii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI