Baálé ilé méjì dèrò kọ́ọ̀tù nítorí ìjà tí wọ́n ń bá ara wọn jà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, July 23, 2021

Baálé ilé méjì dèrò kọ́ọ̀tù nítorí ìjà tí wọ́n ń bá ara wọn jà


Awọn baale ile meji kan, Ṣeun Alade, ẹni ọdun mejilelogoji ati Rafiu Aminu, ẹni ogoji ọdun ti foju ba ile ẹjọ Majisireeti kan to wa ni Ikẹja, ipinlẹ Eko laaarọ oni, ọjọ Ẹti, Furaidee.


Ko si ẹsun ti wọn fi kan wọn nibẹ, bi ko ṣe pe wọn n ja, eyi ti wọn sọ pe wọn n da alaafia aarin ilu laamu.

Awọn mejeeji yii ni wọn sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti agbẹjọro ọlọpaa, ASP Benson Emuerhi fi kan wọn niwaju Onidajọ J. A Adeṣẹgun, to gbọ ẹjọ naa.

Ọjọ kẹta, oṣu to kọja yii la gbọ pe awọn mejeeji kọju ija sira wọn ladugbo Jagundeyi to wa ni Ayọbọ, ipinlẹ Eko.

Wọn ni bi ero ṣe pe le wọn lori to, lati bawọn pari ija naa, ko sẹni to gbọ ninu wọn, ko to di pe awọn ọlọpaa debẹ. Ẹṣẹ yii ni wọn loo tako iwe ofin ọdaran tipinlẹ Eko, tọdun 2015.

Ile ẹjọ naa wa sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹjọ, oṣu kẹjọ, ọdun yii, to si lawọn mejeeji lanfaani lati gba beeli ara wọn pẹlu oniduro kọọkan, ati ẹgbẹrun lọna aadọta, ẹni kọọkan wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI