Àwọn nǹkan tí ẹ kò tún tíì gbọ́ nípa ọ̀rọ Ìgbòho tó ń lọ lọ́wọ́ ní Benin, wọ́n ní ádùrá lọ̀rọ rẹ̀ gbà báyìí - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Friday, July 23, 2021

Àwọn nǹkan tí ẹ kò tún tíì gbọ́ nípa ọ̀rọ Ìgbòho tó ń lọ lọ́wọ́ ní Benin, wọ́n ní ádùrá lọ̀rọ rẹ̀ gbà báyìí


Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, afaimọ ni ko ma jẹ pe orilẹ-ede olominira Benin ni olori ajafẹtọ ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ ti pupọ awọn eeyan mọ si Sunday Igboho yoo ti ṣẹwọn ọdun mọkanlelogun gbako, iyẹn bi wọn ba fi le sọ pe ọkunrin naa jẹbi ẹsun ṣiṣe ayederu iwe irinna ti wọn fi kan an.
 
Ki i ṣe iroyin tuntun mọ pe ọwọ ọlọpaa ilẹ Benin ti tẹ Igboho pẹlu iyawo rẹ, Rọpo, lọjọ Aje, Mọnde to kọja ọsẹ yii. Ọrọ rẹ si lo n lewaju bayii kaakiri orilẹ-ede Naijiria lati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ti ọrọ naa ti jade sita, titi di akooko ta a pari iroyin yii.
 
Latigba tọwọ ti tẹ Igboho la gbọ pe ijọba Naijiria ti n wa gbogbo ọna lati gbe ọkunrin naa pada siluu, lati le ṣe ohun to wa lọkan wọn fun un, ṣugbọn to si n jẹ pabo.
 
Ijẹta, Wẹsidee lo yẹ ki wọn foju Igboho ba ile ẹjọ, ṣugbọn ti ko sẹni to yọju. Ana, Tọsidee ni wọn pada foju oun pẹlu iyawo rẹ, Rọpo ba ile ẹjọ Cour D’Appel De Cotonou, nibi ti wọn ti pada da Rọpo lare wi pe oun ko ni ẹjọ kankan lati jẹ.
 
Bo tilẹ jẹ pe awuyewuye to ti n lọ kaakiri igboro tẹlẹ ni pe adehun wa laaarin ijọba Naijiria ati Benin lori gbigbe eeyan to ba sa wa si eyikeyi ilu mejeeji, eyi tawọn kan n sọ pe adehun naa ko kan awọn ti ọrọ wọn ba ni i ṣe pẹlu ọrọ oṣelu, ṣugbọn ohun to tun n lọ bayii ni pe ko si adehun naa laaarin wọn, ti a ko si ti i le fidi rẹ mulẹ lasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yii tan.
 
Oni, Ọjọbọ, Tọsidee ni ile-ẹjọ naa sun igbẹjọ si, ṣugbọn ti wọn tun ti pada sun un siwaju di ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to n bọ.
 
Ninu ọrọ ti agbẹnusọ fun ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, Ọgbẹni Maxwell Adelẹyẹ fi sita lo ti sọ pe:
"Lanaa, ile ẹjọ ti tu iyawo Igboho, Arabinrin Adeyẹmọ silẹ, nigba ti wọn ri i pe ko ni ẹsun kankan ti wọn le fi kan an, wọn si da iwe irinna orilẹ-ede Germany rẹ pada fun un.

"Awọn agbẹjọro Igboho ti wọn n ṣiṣẹ lori ẹjọ naa sọ pe nnkan pataki meji ọtọọtọ ni ijọba Naijiria ko fi le gbe Igboho kuro nibi to wa: Lara rẹ ni pe ijọba orilẹ-ede mejeeji ko ni adehun kankan ti wọn le fi le gbe Igboho, gẹgẹ bi awuyewuye naa ṣe n lọ.
 
"Ẹlẹẹkeji ni pe ijọba Naijiria ko ti i le sọ pe ẹsun bayii ni Igboho ṣẹ wọn, to mu ki wọn maa wa kaakiri, ati idi ti wọn fi fẹẹ gbe e kuro lọdọ wọn."

Wọn lo ṣee ṣe ki Igboho fi ẹwọn ọdun mọkanlelogun gbara
 
Iroyin to tun tẹ wa lọwọ bayii ni pe o ṣee ṣe ki Igboho fi ẹwọn ọdun mọkanlelogun jura lori iwe irinna ti wọn ri gba lọwọ ẹ, lakooko tawọn ọlọpaa mu ni papakọ ofurufu Cadjèhoun to wa ni Cotonou.

Ọjọ kẹsan-an, oṣu yii ni ileeṣẹ to n ṣeto iwe irinna fawọn eeyan lorilẹ-ede yii, Nigeria Immigration Service (NIS) pariwo sita wi pe Igboho ti n gbiyanju lati salọ kuro ni Naijiria, ati pe awọn ti n ri awọn ẹri kan gba wi pe ọkunrin naa ti n wa ọna bi yoo ṣe gba iwe irinna miran.

Wọn ni bi Igboho ṣe fi Naijiria silẹ, ilẹ Bẹnin lo gba lọ, lati gba iwe irinna wọn, ko le gbabẹ pada si Germany, nibi to ti niwe igbelu, ṣugbọn ti aṣiri pada tu siita.
 
Ọkan lara awọn aṣofin lorilẹ-ede Benin, Ọgbẹni Tolulase nigba to n bawọn akọroyin sọrọ lori ọrọ yii sọ pe orilẹ-ede wọn le kere pupọ loootọ, ṣugbọn awọn maa n tẹle ilana ati ofin ni gbogbo igba.

“Lori ọrọ iwe irinna yẹn, ẹ wo mi bi apẹẹrẹ. Ọmọ ilẹ yii ni mi, ṣugbọn Ijẹbu ni iyawo ti mo fẹ ti wa. A bi ọmọ marun-un funra wa. O bimọ meji ni Naijiria, o si bimọ mẹta ni Benin nibi.

“Mẹta pere lo niwe irinna Benin ninu wọn, awọn meji yooku, pẹlu iyawo mi ko ni iwe irinna yii lọwọ. Ọna kan ṣoṣo to fi le gba a ni bi a ba ṣe igbeyawo labẹ ofin.

“Koda, lẹyin igbeyawo kootu, ki i ṣe ẹsẹkẹsẹ ni wọn maa fun un niwe irinna naa. O maa duro fun ọdun diẹ, nitori pe o gbọdọ tẹle ilana labẹ ofin wa.

“Nnkan akọkọ teeyan gbọdọ kọkọ gba ni kaadi idanimọ, iyẹn National Identity Card. Bayii, bi ẹni naa ki ba a ṣe ọmọ ilu, ọna kan ṣoṣo ti iru ẹni bẹẹ le fi gba kaadi idanimọ ni pe ko fẹ obinrin Benin labẹ ofin.

“Ṣe ẹ wa ri i pe ko rọrun rara. Fun idi eyi, beeyan ba lọ gba ayederu iwe irinna, aṣiri maa tu sita nitori pe ẹni naa ko ni kaadi idanimọ. Wọn maa ri gbogbo aṣiri yẹn.

“Kaadi naa gbọdọ ni orukọ mọlẹbi. Awọn mẹta si marun-un ninu awọn mọlẹbi gbọdọ jẹ ki ijọba mọ pe ọkan lara wọn lo jẹ, ati pe lati kekere ni.

“Lẹyin ti wọn ba jẹri tan ni ile ẹjọ yoo ṣẹṣẹ fun ẹni naa ni kaadi yii, oun si leeyan le fi gba iwe irinna. Ṣugbọn to ba jẹ pe ayederu kaadi ni ẹni naa n gbe kaakiri, ijiya to wa nibẹ ni pe, iru ẹni bẹẹ yoo lọ si ẹwọn ọdun mọkanlelogun. Ẹṣẹ nla gidi gan an ni.

“Ati pe, ki i ṣe ẹni to gba ayederu kaadi naa nikan lo maa gba idajọ yi o, gbogbo awọn ti wọn mọ nipa ẹ ni wọn jọ maa foju wọn ba ile ẹjọ.

“Lori ọrọ Oloye Sunday Igboho, ijọba Benin yoo ṣe iwadii kikun lati mọ gbogbo awọn to wa nidi bo ṣe gba iwe irinna naa patapata.”
 
Ni bayii, pupọ awọn ololufẹ Igboho ni wọn ti n gba awọn eeyan, paapaa awọn ọmọ Yoruba kaakiri agbaye lamọran wi pe ki wọn dide adura fun un, nitori pe ọna kan ṣoṣo to le fi bọ nibẹ naa ni adura.

1 comment:

  1. Oba togba Daniel lowo kin-ninu�� yio bawa gba aja fun eto omo yoruba lowo awon eni ibi amin

    ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI