Bí wọ́n ṣe mú Kanu ati Igboho ti fi hàn pé òmìnira ti súnmọ́ etílé - Gbajúmọ̀ pásítọ̀ pariwo síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 21, 2021

Bí wọ́n ṣe mú Kanu ati Igboho ti fi hàn pé òmìnira ti súnmọ́ etílé - Gbajúmọ̀ pásítọ̀ pariwo síta


Pasitọ agba fun ijọ Senior Awaiting The Second Coming Of Christ Ministry, Adewale Giwa ti gba gbogbo ọmọ Yoruba ati Igbo lamọran wi pe ki wọn di ara wọn mu ṣinṣin ninu ija ominira ti wọn wa ninu ẹ lọwọ.

O sọ pe asiko fun gbogbo wọn lati gba ominira kuro lọwọ ijọba amunisin ti sunmọ etile. Bẹẹ lo tun sọ pe ko sẹni to le da ominira naa duro bo ti le wu ko ri.

"Ko sẹni to le da ominira to n bọ fawọn ọmọ Naijiria kuro lọwọ ijọba Fulani duro. Bi wọn ba n ṣe dunkooko, ti wọn n fiya jẹ awọn ajijangbara, bẹẹ naa ni awọn ọmọ Naijiria yoo maa sunmọ ominira wọn."

"Idunkooko ati ọwọ lile ti wọn n lo yoo tun maa fun awọn ọmọ Naijiria lagbara si i ni.  Awọn ọmọ Naijiria yoo jade pẹlu agbara ati okun lile, ati pe ina yoo tan lẹyin gbogbo rẹ.

"Awọn ọmọ Yoruba ati Igbo gbọdọ di ara wọn mu ṣinṣin. Ọlọrun yoo dide pẹlu iyalẹnu lati pa awọn alagbara to n dunkooko run. Awọn ọmọ Naijiria ko mọ pe Aarẹ Muhammadu Buhari yoo ṣe wọn baṣubaṣu ki wọn too pinnu lati dibo fun un lọdun 2015.

"Ju gbogbo rẹ lọ, aṣiṣe naa ti waye,a si ti kẹkọọ. Awọn ti ko pọ ko le ba ọpọ ja! Ọpọ ọmọ Naijiria ni wọn ti sunmọ ominira wọn, o maa ṣẹlẹ laipẹ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI