Ìdí pàtàkì tíjọba Kwara fi wọ́gilé ayẹyẹ ọdún Durbar tọdún yii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 21, 2021

Ìdí pàtàkì tíjọba Kwara fi wọ́gilé ayẹyẹ ọdún Durbar tọdún yii


Ana ti i ṣe ọdun Ileya, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq wọgile ayẹyẹ ọlọdọọdun kan ti wọn pe ni Durbar.

Oni, Ọjọru, Wẹsidee lo yẹ ki ayẹyẹ naa waye, gẹgẹ bi wọn ti ṣe la a kalẹ, ṣugbọn ti ijọba ipinlẹ naa sọ pe ko ni le waye mọ.

Ko si nnkan meji ti wọn lo fa igbesẹ yii, bi ko ṣe ti eto aabo ti wọn o ṣee ṣe mẹhẹ lasiko ayẹyẹ naa.

Wọn lawọn kan ti gbaradi lati da ayẹyẹ naa ru pẹlu ikọlu nla, olobo yii lo ta si ijọba leti, ti wọn fi kede pe konikaluku jokoo sile ẹ, ki wọn si gbagbe ayẹyẹ naa lọdun yii.

Ijọba ipinlẹ naa sọ pe ẹdun ọkan nla lo jẹ fawọn wi pe ayẹyẹ naa ko ni i waye, nitori pe ohun nikan ni wọn tun n ri gẹgẹ bi ọna lati gbe aṣa ati iṣe wọn larugẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI