E pàdé SaboCity Ọlọ́jà-obìnrin lórí èto Ìrírí Gbajúmọ̀ l'ọse yii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, July 19, 2021

E pàdé SaboCity Ọlọ́jà-obìnrin lórí èto Ìrírí Gbajúmọ̀ l'ọse yii


Ki i ṣe ti ẹnu tabi asọdun rara pe ko si eto meji tawọn eeyan tun n gbọ kaakiri ilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ati agbegbe rẹ lakooko yii, bi ko ṣe eto ti ọkan lara awọn gbajugbaja sọrọsọrọ nni, Ọgbẹni Saburi Ọladeji, ẹni tọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si SaboCity Ọlọja-Obinrin n ṣe nileeṣẹ redio Smash 88.1FM.

Gbogbo Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ-ọsẹ ni SaboCity maa n ṣe eto naa to pe ni IRIRI GBAJUMỌ, laaarin aago mọkanla aarọ si mejila ọsan. nibẹ lo ti n gbe oriṣiriṣi alejo ọlọkan-o-jọkan wa lati sọ iriri wọn nipa iṣẹ ti wọn yan laayo.

Bawọn oloṣelu ṣe sọ eto naa ti kọmu-o-lọ, bẹẹ lawọn ọlọja kekeeke ati nla-nla, to fi mọ awọn ọtọkulu lawujọ ko le fi eto naa ṣere rara.

Yatọ si eyi, SaboCity yoo tun wa lori eto to pe ni 'Onilu Ko Ni i Jẹ Ko tu', eyi to maa n waye ni gbogbo Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, nileeṣẹ redio Star 91.5FM to wa niluu Ibadan, laaarin aago mẹfa si aago meje irọlẹ.

Fun ipolowo ọja tabi alaye lẹkunrẹrẹ, ẹ pe SaboCity sori awọn ẹrọ ibanisọrọ yii: 08030818029,
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI