Èyí ni bí wọ́n ṣe fẹ́ẹ́ sìnkú Dàpọ Ọṣìn, gbajúmọ̀ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó kú l'Ékòó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, July 19, 2021

Èyí ni bí wọ́n ṣe fẹ́ẹ́ sìnkú Dàpọ Ọṣìn, gbajúmọ̀ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó kú l'Ékòó


Awọn mọlẹbi oloogbe Dapọ Ọṣin, gbajugbaja sọrọsọrọ ori redio ati tẹlifiṣan to jade lọsẹ to kọja ti sọ pe ọsẹ yii ni wọn yoo sinku ẹ, lẹyin ayẹyẹ ọdun Ileya.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, oriṣiriṣi ilana ọlọkan-o-jọkan ni wọn ti la kalẹ fun ayẹyẹ isinku Oloogbe naa niluu Eko.

Ọjọruu, Wẹside ni wọn yoo ṣe isin orin onigbagbọ fun un ni D A Block 1, Federal Bus Stop, federal Housing Estate, Ipaja, l'Ekoo, bẹrẹ lati aago mẹta ọsan.

Ọjọbọ, Tọsidee ni wọn yoo ṣe aṣalẹ awọn oṣere {Artist Night} nibi kan naa, bẹrẹ lati aago marun irọlẹ.

Ọjọ Ẹti, Furaidee ni wọn yoo tẹ Dapọ Ọṣin si afẹfẹ rere ni Tom Island, Badore Ajah, l'Ekoo, bẹrẹ lati aago mẹwaa aarọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI