Ẹ wo adigunjalè tó pàdé ikú òjijì lẹ́nu iṣẹ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 18, 2021

Ẹ wo adigunjalè tó pàdé ikú òjijì lẹ́nu iṣẹ́


Yoruba ti wọn sọ pe ọjọ gbogbo ni ti ole, ọjọ kan ṣoṣo bayii ni ti olohun ko parọ rara, gẹlẹ ni ọrọ naa si lọ ni ibamu pẹlu bi adigunjalè ti ẹ n wo yii ṣe pade iku òjijì, to si sọda sọrun alakeji. 

Wọn ni to ba n ra kooro, yoo ti de ajulẹ ọrun lakooko ti a pari iroyin yii. 

 Ijẹta, ọjọ Ẹti, Furaidee la gbọ pe adigunjalè naa ba Ọlọrun lalejo. Asiko toun pẹlu awọn ẹmẹwa rẹ n ṣiṣẹ ibi wọn lọwọ loju ọna Ṣagamu silu Ijẹbu Ode ni wọn sọ pe omi tẹyin wọgbin wọn lẹnu. 

Gẹgẹ bi AWIKONKO ṣe gbọ, wọn ni ṣe lawọn adigunjalè naa da mọto akero kan duro, nitosi fasiti Southwestern, ti wọn si bẹrẹ si i fibọn atawọn nnkan ija oloro ja awọn eeyan lole dukia wọn.

Ibẹ la gbọ awọn to n kọja lọ ti ta ileeṣẹ ọlọpaa Odogbolu lolobo, ti wọn loju ẹsẹ ni wọn ti debẹ.

Wọn ni bawọn adigunjale naa ṣe foju kan awọn ọlọpaa ni wọn ti kọju ibọn si wọn, ti awọn mejeeji si dabọn bolẹ funra wọn fun bi iṣẹju marunlelogoji, ko to di pe ibọn ba ọkan lara wọn, ti awọn yooku si juba ehoro.

Asiko ti wọn n gbe e lọ si ọsibitu lati tọju ẹ ni wọn sọ pe o gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra, ti ẹlẹmin si gba a.

Edward Awolọwọ Ajogun yo jẹ ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, nigba to n sọrọ paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ lori awọn to na papa bora, ki ọwọ ba a le tẹ wọn.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI