Pápákọ̀ òfurufú ipinlẹ Ogun yóò parí lọ́dún tó ń bọ̀ - Gómìnà Abíọ́dún - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Sunday, July 18, 2021

Pápákọ̀ òfurufú ipinlẹ Ogun yóò parí lọ́dún tó ń bọ̀ - Gómìnà Abíọ́dún


Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ti sọ pe ki gbogbo ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa lọ fi ọkan wọn balẹ nitori pe ọdun to n bọ, iyẹn 2022 lawọn ti la kalẹ wi pe papakọ ofurufu akẹru, Cargo Airport  ti wọn ti bẹrẹ iṣẹ rẹ yoo pari.

O ni ko si nnkan to le da iṣẹ to ti bẹrẹ naa duro, bi ko ṣe pe ki awọn agbaṣẹṣe ti wọn gbé iṣẹ naa le lọwọ tete pari rẹ.

Ana, Satide, Abamẹta ni Gomina Abiọdun fidi ọrọ naa mulẹ nibi ipolongo idibo ijọba ibilẹ ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ti wọn ṣe lọ siluu Ikẹnnẹ.

Nibẹ lo ti sọ pe oun ko ni i tẹriba fun awọn alatako ti wọn ko fẹ ki awọn ọmọ ipinlẹ naa, paapaa awọn eeyan lati ilu Ikẹnnẹ jẹ anfaani ijọba awaarawa.

Ilu Iliṣan-Rẹmọ,ijọba ibilẹ Ikẹnnẹ ni won fẹẹ gbe papakọ ofurufu naa kalẹ si, bo tilẹ jẹ pe ijọba ana labẹ iṣakoso Sẹnetọ Ibikunle Amosun ti sọ pe Wasinmi ni wọn fẹẹ ṣe e si tẹlẹ.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe:
"Ọkọ baalu yoo bẹrẹ si i balẹ siluu Ikẹnnẹ nibi. Awọn kan n kọ papakọ ofurufu, awọn kan n kọ papakọ ofurufu tibilẹ, inu n bi wọn, wọn si n ba wa ja. Wọn sọ pe wọn ko le ri ibi ti a maa ṣe e si nibi, mo si jẹ ko ye wọn pe irọ ni wọn n pa.

"Emi ni gomina ipinlẹ Ogun bi a ṣe n sọrọ yii. Ọwọ mi ni iṣu ati ọbẹ wa. Mo si maa pin in bo ba ṣe wu mi.

"A ti ri ibi ti a maa kọ papakọ ofurufu naa si nibi, nigba ti ọdun to n bọ yoo ba fi pari, a maa fi papakọ ofurufu naa lelẹ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI