Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní kọ́ọ̀tù, àti anfààní tuntun tí wọ́n fún Sunday Ìgbòho - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 27, 2021

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní kọ́ọ̀tù, àti anfààní tuntun tí wọ́n fún Sunday Ìgbòho


Fun bi i wakati mẹtala gbako ni igbẹjọ naa fi waye nile ẹjọ Cour De’appal De Cotonou, to wa lorilẹ-ede olominira Benin, nitori Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ ti awọn eyan tun mọ si Sunday Igboho, olori ajijangbara fun ominira ilẹ Yoruba nile-loko.
 
Nibẹ ni awọn eeyan, paapaa awọn ololufẹ ati alatilẹyn Igboho kaakiri ti n duro lati mọ ibi ti ọrọ ọhun yoo pada ja si.
 
AWIKONKO gbọ pe latigba ti iroyin ti jade sita wọn ti mu ọkunrun yii pẹlu iyawo rẹ nilẹ Benin lawọn ọmọ Yoruba lagbaye ti wọle adura wi pe Oloye Sunday Igboho ko ni i ku sinu wahala ati idaamu yii, ati pe yoo jade layọ, ti oju yoo si ti ijọba Naijiria, aridaju rẹ to fi han lawọn oju opo IROYIN AWIKONKO.
 
Awọn agbẹjọro Igboho ni wọn gbiyanju agbara wọn, ki ile ẹjọ naa le da a silẹ lati maa lọ, paapaa ko si tun ni anfaani si ayẹwo ilera pipe. Igbẹjọ ọhun to bẹrẹ laago mejila ọsan, lo pari pari ni nnkan bi aago mọkanla aabọ si mejila alẹ ana, Mọnde (Aago orilẹ-ede Naijiria), bo tilẹ jẹ pe isinmi n waye laaarin ẹ loore-koore.

Agbẹjọro ti ko din ni mẹfa la gbọ pe ijọba orilẹ-ede Naijira gbe dide lati tako Oloye Sunday Igboho, ẹyi awọn agbẹjọro agbaye ti wọn gbọ ede Faranse ati oyinbo dijudiju wa lara wọn.

Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ, ọkan lara awọn agbẹjọro fun Igboho, Pẹlumi Ọlajẹngbesi sọ pe idaniloju ti n wa pe wọn yoo fi Oloye Sunday Igboho silẹ laipẹ, nitori pe awọn ti ba ẹjọ naa debi to ni apẹẹrẹ rere.
 
Ṣaaju asiko yii ni ile-ẹjọ ti le awọn akọroyin atawọn alatilẹyin Igboho danu kuro ni ayika ile-ẹjọ, lati le jẹ ki wọn roju raaye sọrọ daadaa. Oloye Sunday Igboho ati iyawo rẹ, Rọpo nikan ni wọn tun fun laaye ninu yara ile-ẹjọ ọhun.

Ile-ẹjọ naa farabalẹ ṣe iwadii kikun lori ẹsun ti ijọba orilẹ-ede Naijiria fi kan Igboho, eyi ti wọn sọ pe ọkunrin naa n ṣe fayawọ ibọn, bẹẹ lo n gbe ibọn rin, ati pe o n da ija ẹlẹyamẹya silẹ laaarin ilu.

Lẹyin o rẹyin, ile-ẹjọ gbe idajọ kalẹ wi pe ki wọn mu Oloye Sunday Igboho kuro ni ahamọ ọlọpaa to wa tẹlẹ, ki wọn si lọọ fi sibi ti aaye yoo ti gba a daadaa.
 
Ibi ipamọ ti ile-ẹjọ paṣẹ pe ki wọn fi Igboho si yii ko ni i jẹ ahamọ awọn ọdaran, bi ko ṣe ọgba ẹwọn ti yoo ti ni alaafia fun ara rẹ, nibẹ si ni yoo ti lanfaani si itọju to peye.
 
Ibrahim Salami, ọkan lara awọn agbẹjọro Igboho jẹ ka mọ pe ahamọ Cotonou Civil Prison nibi ti wọn fi ọkunrin naa si, ko si si ni Brigade Criminelle to wa tẹlẹ mọ.
 
Nibẹ ni yoo si ti lanfaani si ounjẹ, iwẹ, iyagbẹ, omi ati bẹẹbẹẹlọ.

1 comment:

PÍN-IN KÁÀKIRI