Ìjọba Kwara bu ọwọ́ lu owó oṣù ìgbéga àjẹẹ́lẹ̀ ọdún mẹ́rin fáwọn olùkọ́ SUBEB - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 27, 2021

Ìjọba Kwara bu ọwọ́ lu owó oṣù ìgbéga àjẹẹ́lẹ̀ ọdún mẹ́rin fáwọn olùkọ́ SUBEB


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara, lanaa, ọjọ Aje, Mọnde ti bu ọwọ lu owo oṣu igbega tuntun ti ijọba ana ti jẹ awọn olukọ SUBEB silẹ fun ọdun mẹrin.
 
Awọn olukọ SUBEB ti ko din ni ẹgbẹrun mẹwaa la gbọ pe wọn yoo gba ẹtọ wọn lat ọdun mẹrin sẹyin ti wọn ti gba igbega, ṣugbọn to jẹ pe owo oṣu ti wọn n gba tẹlẹ naa ni wọn ṣi n gba latigba yii wa.
 
Alaga ẹgbẹ SUBEB, (Kwara State Universal Basic Education Board, KWSUBEB), Ọjọgbọn Ṣhehu Raheem Adaramaja lo fidi ọrọ yii mulẹ lasiko to n fi awọn ohun elo amuṣẹya tijọba ipinlẹ naa ṣẹṣẹ fun wọn lọlẹ.
 
Gomina AbudulRahman AbdulRazaq la gbọ pe o ra awọn nnkan elo amuṣẹya naa bi i mọto, ọkada, foonu atawọn nnkan mi in ti yoo jẹ ki eto ẹkọ dagbasoke nipinlẹ Kwara fawọn olukọ atawọn olukọ SUBEB mi in.
 
Ọdun 2017 la gbọ pe awọn eeyan yii ti gba igbega gbẹyin, ṣugbọn to jẹ pe b wọn ṣe gba igbega naa, owo oṣu ti wọn n gba tẹlẹ naa ni wọn ṣi n gba.
 
Adaramaja nigba to n sọrọ tun fi ye awọn eeyan wi pe ijọba tun ti bu ọwọ lu idanwo igbega fun ọdun 2017, 2018, 2019 ati 2020, to si ni ọjọ keji ati ọjọ karun-un, oṣu kẹjọ ọdun yii ni yoo waye.
 
Gomina AbdulRazaq, ti igbakeji rẹ, Kayọde Alabi ṣoju fun, nigba to n sọrọ sọ pe gbogbo ọna ni ijọba n wa lati ri i pe eto ẹkọ nipinlẹ naa ba ti eto ẹkọ igbalode agbaye mu.
 No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI