Ewé sunko! Èyí ni bí ọwọ́ ṣe tẹ Sunday Igboho ní Cotonou - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 20, 2021

Ewé sunko! Èyí ni bí ọwọ́ ṣe tẹ Sunday Igboho ní Cotonou


Ọwọ ọlọpaa ti tẹ ajijangbara ominira fun ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmo, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Sunday Igboho. Orile-ede olominira Benin ti wọn tun n pe ni Cotonou la gbọ pe ọwọ ti tẹ ẹ lalẹ ana, Mọnde.

Papakọ ofurufu ti Cotonou Cadjehoun la gbọ pe ọwọ ti tẹ Igboho lakooko to fẹẹ na papa bora kuro nilẹ Afrika.

Ọsẹ mẹta lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ orile-ede yii lọ fọ ile Igboho, ti wọn si kede sita wi pe wọn ti n wa a lori ẹsun wi pe o n ko ibọn pamọ sinu ile.

AWIKONKO gbọ pe oni, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni wọn yoo gbe Igboho wọ orile-ede Naijiria pada, gẹgẹ ba a ṣe gbọ lati le foju ba ile ẹjọ.

Ko to di pe Igboho na papa bora, a gbọ ijọba orile-ede yii ti ta gbogbo ileeṣẹ eleto aabo patapata lolobo wi pe ki wọn ba wọn mu Igboho nibikibi ti wọn ba ti kofiri rẹ

Ọkan lara awọn agbẹjọro fun Igboho, Pẹlumi Ọlajẹngbesi nigba to n sọrọ sọ pe oun ko ti i le sọ nnkankan, ayafi toun ba ṣẹṣẹ gba aṣẹ lọwọ adari wọn, Yọmi Aliru.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ DSS, Peter Afunanya naa ko ti i sọrọ titi dasiko ta a kọ iroyin yii tan

1 comment:

  1. Fun akoroyin awikonko, ona ti egba gbe iroyin yi jade gege bi ero Temi okudia kaato, koye kegbe pe ewe sun ko bi igba pe enfi omoyayin se yeye lojo loju Temi, eforijinmi o tobada bi ese ese

    ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI