Nítorí wàhálà Ọffa àti Erinlẹ, AbdulRazaq gbé ìgbìmọ̀ àgbà ńlá dìde láti yanjú ẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 20, 2021

Nítorí wàhálà Ọffa àti Erinlẹ, AbdulRazaq gbé ìgbìmọ̀ àgbà ńlá dìde láti yanjú ẹ̀


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara lọjọ Aje, Mọnde ana ti gbe igbimọ agba nla kan dide lati yanju gbogbo wahala ati aawọ to n ṣẹlẹ laaarin ilu Ọffa ati Erin-Ilẹ nipinlẹ naa.
 
Wahala naa la gbọ pe o ti pẹ to ti n ṣẹlẹ laaarin awọn ilu mejeeji yii, eyi ti wọn ni ẹmi ati dukia awọn eeyan ti lọ si i.
 
Gomina tẹlẹri, Cornelius Adebayọ la gbọ pe wọn fi ṣe alaga igbimọ yii, ti awọn bi i Adajọ-fẹyinti Saidu Salihu; Alaaji LAK Jimoh; Oloye Titus Aṣhaolu; Sẹnetọ Simeon Ajibọla; Alaaji Abubakar Ndakene; Sẹnetọ Mohammẹd Ahmẹd; Amọfin Sabitiyu Kikẹlọmọ Grillo; ati Ọjọgbọn Hassan Saliu toun jẹ akọwe.
 
Nigba to n fi igbimọ naa lelẹ nileeṣẹ ijọba to wa niluu Ilọrin, Gomina AbdulRazaq gba igbimọ naa lamọran lati ri i daju pe wọn ṣe ojuṣe wọn lakooko to yẹ, ati pe ko to o pẹ ju.
 
Pẹlu igbimọ yii, a gbọ pe wahala ati aiṣọkan naa yoo yanju patapata, ti ko si ni i gberi mọ. Gbogbo awọn nnkan to ti n da wahala silẹ tipẹ yii ni wọn yoo wa iyanju si.
 
AbdulRazaq ni wahala to ṣẹlẹ gbẹyin loṣu kẹta ọdun yii n kan ijọba lominu pupọ, to si n mu ifasẹyin ba eto ọrọ aje ati idagbasoke ipinlẹ naa
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI