Èyí ni bí àsọtẹ́lẹ̀ Wòlíì Ayọdele nípa South Africa ṣe wá sí ìmúṣẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 15, 2021

Èyí ni bí àsọtẹ́lẹ̀ Wòlíì Ayọdele nípa South Africa ṣe wá sí ìmúṣẹ


Òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí ni Wòlíì Elijah Ayọdele gbé ìwé àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ jáde, níbi tí ogunlọ́gọ̀ àwọn akọ̀ròyìn tí péjú pésẹ̀ síbẹ̀. 

Nibẹ ni Wolii Ayọdele, Aláṣẹ ati oludasklẹ ṣọọṣi INRI Evangelical to wa niluu Eko ti sọ àwọn nnkan ti yoo ṣẹlẹ̀ lorileede South Africa, paapaa nipa Aarẹ ana, Jacob Zuma ti wọn ju sẹwọn. 

O ni ifẹhonuhan ati ogun yoo dide, ti awọn eeyan yoo si bẹ̀rẹ̀ si i pa ara wọn, ati pe agbara awọn agbófinró ati awọn eleto aabo ko ni i ka wahala naa. 

Wolii Ayọdele tẹsiwaju pe awọn araalu yoo dide lodi si ijọba nitori bi wọn ṣe n tẹ ofin loju mọlẹ lori ẹsun ikowojẹ ti wọn fi kan Zuma.

Bi nnkan si ṣe n lọ lasiko yii lorileede ọhun, ifẹhonuhan nla lo ti bẹ̀rẹ̀, ti awọn eeyan si n da wahala sílẹ̀ gidigidi. Ọ̀pọ̀ ṣọọbu la gbọ pe wọn ti ja, ti wọn si ti ji awọn ọjà ati ẹrú inu rẹ ko salọ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI