Nnkan ṣe, Wọn tun ti ji gbajumọ ọba alaye l'Ajaokuta gbe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 14, 2021

Nnkan ṣe, Wọn tun ti ji gbajumọ ọba alaye l'Ajaokuta gbe


Awọn agbebọn kan ti ko ti i sẹni to le sọ nipa wọn la tun gbọ pe wọn ti ji ọba alaye kan, Adogu tilu Eganyi, to wa nijọba ibilẹ Ajaokuta, ipinlẹ Kogi, Alaaji Mohammed Adembe gbe salọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa lo fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ laipẹ yii wi pe loootọ ni, ati pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn lati ri kabiyesi naa gba pada kuro lọwọ awọn oniṣẹ ibi wọnyii.
 
DSP William Aya, to jẹ alukoro awọn ọlọpaa nigba to n sọrọ sọ pe nnkan bi aago marun-un kọja ogun iṣẹju, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ana loju ọna Okene si Eganyi, ipinlẹ na.
 
A gbọ pe asiko ti kabiyesi naa n pada si aafin rẹ lawọn agbebọn yii da a lọna nibi ti ọna ko ti dara, ti wọn si dabọn bolẹ lati ji i gbe wọnu igbo lọ.
 
Iroyin to tun tẹ wa lọwọ sọ pe ki i ṣe kabiyesi nikan lo wa ninu mọto naa, gbogbo awọn ti wọn jọ wa nibẹ patapata la gbọ pe ko si eyi ti wọn fọwọ kan ninu wọn, yatọ si kabiyesi nikan ti wọn gbe wọnu igbo pẹlu ibọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI