Ìgbésẹ bẹ̀rẹ̀ lábẹ́lẹ̀ láti tú Sunday Ìgbòho sílẹ̀ nílé-ẹjọ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 26, 2021

Ìgbésẹ bẹ̀rẹ̀ lábẹ́lẹ̀ láti tú Sunday Ìgbòho sílẹ̀ nílé-ẹjọ́


Iroyin tuntun to tẹ wa lọwọ bayii ni pe awọn adajọ ati agbẹjọro nile ẹjọ Cour D’Appel De Cotonou ti bẹrẹ ipade ikọkọ lori ọna bi wọn yoo ṣe pari ẹjọ naa lonii, ta a si gbọ pe o ṣee se ki wọn fi olori ajijangbara ilẹ Yoruba silẹ lati maa lọ layọ ati alaafia.

AWIKONKO gbọ pe gbogbo awọn akọroyin ati awọn alatilẹyin Oloye Sunday Igboho ni wọn le jade kuro ninu ile ẹjọ naa lati lẹ jẹ ki wọn mọ ọna ti wọn fẹẹ gba yanju ẹjọ yii.
 
Nigba to n fidi rẹ mulẹ, Ibrahim Salami to jẹ agbẹjọro Igboho niluu Cotonou, Benin sọ pe:
 
“Nigba to kuro ni Naijiria, ọna ẹyin lo gba wọ Benin. Igba to de papakọ ofurufu lawọn agbofinro daa duro, wi pe wọn n wa a. Ko ṣe nnkan to tako ofin ilẹ Benin. Wọn ko ri iwe irinna Benin lọwọ rẹ nigba ti wọn daa duro. Iwe irinna ti Naijiria ati iwe igbelu Germany ni wọn ba lọwọ ẹ. Ko nilo fisa lasiko naa.

“Nigba ti a ṣagbeyẹwo ẹjọ naa daadaa, a ṣakiyesi wi pe ijọba Naijiria ko ti i kọwe ẹsun wi pe wọn fẹẹ gbe e pada sile. Ohun kan ṣoṣo ti wọn n sọ ni pe awọn n wa lori ẹsun ọdaran to ni lati jẹ. Ariyanjiyan wa ni pe idi ti wọn fi daa duro ni ti bi ijọba Naijiria ṣe lawọn n wa. Ko si aridaju kankan to le fidi rẹ mulẹ wi pe ọdaran ni.”

 

Bakan naa, Ọgbẹni Maxwell Adelẹyẹ to jẹ agbẹnusọ ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua nigba toun naa n sọrọ lonii, sọ pe wọn ti faaye silẹ fun Sunday Igboho lati ba iyawo rẹ, Rọpo sọrọ, bẹẹ lawọn oniṣegun oyinbo ti yọju si i lati wo ilera rẹ.

O sọ pe o ti n da awọn loju wi pe wọn maa tu Sunday Igboho silẹ laipẹ.

2 comments:

PÍN-IN KÁÀKIRI