Igboho! Gani Adams sọ ìpinnu ìjọba àpapọ̀ lórí ọ̀rọ̀ àwọn ajìjàngbara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 21, 2021

Igboho! Gani Adams sọ ìpinnu ìjọba àpapọ̀ lórí ọ̀rọ̀ àwọn ajìjàngbara


Aarẹ Ọna Kankanfo ilẹ Yoruba, Oloye Iba Gani ti sọ pe gbogbo igbesẹ ti ijọba apapọ orilẹ-ede Naijiria n gba ni lati pa gbogbo awọn ajijangbara orilẹ-ede yii lẹnu mọ.

Iba Gani Adams lo sọrọ yii ninu atẹjade to fi sita lati ọwọ amugbalẹgbẹ rẹ lori ọrọ iroyin, Kẹhinde Aderẹmi lonii, nibi to ti sọ pe ọwọ ti ijọba orilẹ-ede yii fi n mu ọrọ eto aabo ku diẹ kaato.

O ni bi ijọba apapọ orilẹ-ede Naijiria ṣe n mu ọrọ Sunday Adeyẹmọ, Igboho bi ọdaran ko ba eto oṣelu awaarawa lọ rara.

"Ọrọ Igboho ti fi n han pe ijọba apapọ fẹẹ kapa gbogbo awọn olufẹhonuhan, eyi ko si ba eto oṣelu awaarawa mu, eyi to ṣee ṣe kawọn araalu kẹyin ijọba, paapaa julọ, ijọba to de ipo agbara nipa  ireti kikun to mu atilẹyin lati ọdọ awọn eeyan jade nilẹ Yoruba.

"Mo ro pe ṣe lo yẹ ki ijọba apapọ rọra ṣe ọrọ ọkunrin yii, nitori pe bi wọn ba gbiyanju lati fi ẹlẹyamẹya mu ọrọ ipe fun ominira, a jẹ pe wọn fẹ ki ina jo lori orule orilẹ-ede yii niyẹn.

"Bi àpẹẹrẹ, ọrọ wi pe a fẹẹ da duro ki i ṣe ọrọ ọjọ kan. Nipasẹ ifiyajẹni ọlọjọ pipẹ, ọjẹlu ati iṣakoso awọn adari buburu lo fi dide.

"Fun idi eyi, ijọba yoo ṣe aṣiṣe nla bi wọn ba pinnu lati yi ọrọ awọn to n pe fun ominira idasilẹ orilẹ-ede Yoruba si ọrọ ọdaran tabi ọta ilu.

"Igboho ni ẹtọ ai ominira rẹ. Ko si nnkan to buru nibẹ to ba bẹbẹ fun ibi aabo lorilẹ-ede olominira Benin, bẹẹ lo si tun le bẹbẹ fun ibi isadi yii lorilẹ-ede to ba wu, iyẹn to ba ro pe ẹmi oun wa ninu ewu nilu rẹ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI