Ìjọba Nàìjíríà yóò kùnà láti mú Sunday Igboho lágbára Ọlọ́run - Agbẹnusọ Igboho - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 22, 2021

Ìjọba Nàìjíríà yóò kùnà láti mú Sunday Igboho lágbára Ọlọ́run - Agbẹnusọ Igboho


Agbẹnusọ fun Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ, ti awọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho, Ọgbẹni Ọlayọmi Koiki ti sọ pe gbogbo igbesẹ tijọba apapọ orilẹ-ede Naijiria n gbe lati tẹri ọkunrin naa ba ko ni i wa si imuṣẹ pẹlu ogo Ọlọrun.
 
Ọlayọmi Koiki lo sọrọ naa laaarọ oni, Ọjọbọ, Tọsidee ninu fọnran to ṣe lori ikanni ayelujara rẹ.
 
Koiki sọ pe aago mẹwaa aarọ yii ni igbẹjọ naa bẹrẹ nile ẹjọ giga tilẹ olominra Benin lati mọ nnkan ti yoo jẹ ireti ọga oun.
 
“Aago mẹwaa aarọ yii ni wọn yoo jokoo nile-ẹjọ Benin. Ile-ẹjọ naa ni yoo sọ ireti boya wọn yoo gbe Igboho pada si Naijiria, nibi to fẹẹ fi silẹ, eyi ti yoo fun awa naa lanfaani lati mọ nnkan to fẹẹ ṣẹlẹ.

“A mọ gbogbo ipinnu ti ijọba Naijiria fẹẹ ṣe, bi wọn ba fi le ri Igboho gbe pada si Naijiria la ti mọ, ṣugbọn wọn yoo kuna nipa oore ọfẹ Ọlọrun.

“Ipinnu wọn ni lati mu Igboho, ṣugbọn Ọlọrun dide lati ja fun un.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI