Rádaràda! Àwọn pásítọ̀ tí a dá dúró kò so èso rere ni jàre - Oyedepo pariwo síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 22, 2021

Rádaràda! Àwọn pásítọ̀ tí a dá dúró kò so èso rere ni jàre - Oyedepo pariwo síta


Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi Living Faith Church Worldwide, ti awọn eeyan tun mọ si Winners Chapel Worldwide, Biṣọọbu David Oyedepo ti sọ idi pataki to fi le awọn pasito ti ko din ni ogoji danu lẹẹkan ṣoṣo.
 
O ni gbogbo wọn ni ko so eso rere lawọn ṣọọṣi ti wọn gbe le wọn lọwọ lati ṣakoso rẹ, bi ko ṣe pe owo oṣu nikan ni wọn n gba.
 
Laipẹ yii ni ọkan lara awọn pasitọ ti wọn da duro naa, Peter Godwin pariwo sita ninu fọnran to gbe sori ikanni ayelujara, nibi to ti fẹsun kan awọn adari ijọ naa, to si lohun ti wọn ṣe ku diẹ kaato. Ọkunrin ọhun loun pẹlu awọn pasito ti ko din ni ogoji ni wọn da duro lojiji ninu ṣọọṣi Winners.

Oyedepo nigba to n fidi rẹ mulẹ l'Ọjọru, Wẹsidee ana, o sọ pe awọn ko le maa kawọ gbera mọ, lati maa wo gbogbo awọn oṣiṣẹ wọn ti wọn ko so eso rere bawọn ṣe lero.

"Nigba ti a gba awọn pasitọ ẹgbẹrun meje, ayelujara ti ku nigba naa. A ni awọn oṣiṣẹ ti a n san owo fun to pọ ju pupọ awọn ipinlẹ to wa lorilẹ-ede Naijiria lọ, ti a ko si jẹ eyikeyi ninu wọn lowo oṣu ri.

"A sọ fawọn pasitọ naa wi pe ki wọn maa lọ nitori pe wọn ko so eso rere. Pupọ awọn ijọ ti a kọ lo jẹ pe wọn ko le san owo ti a fi kọ ijọ naa pada lọgbọn ọdun si asiko yii. A ko ni le ni suuru mọ fun ikuna nibi.

"A ti kọ ṣọọṣi to le ni ẹgbẹrun kan lawọn igberiko kaakiri, to jẹ pe laaarin ọgbọn ọdun si akooko yii, wọn ko le ri owo ti a fi kọ ṣọọṣi naa san pada, wọn ko le ri iru owo bẹẹ tujọ, pẹlu bi ọkọọkan wọn ṣe le ni miliọnu mẹrinla naira ti a fi pari wọn. Ijeere ọkan awọn eeyan la n le kaakiri, ki i ṣe owo to n wọle.

"Awọn eeyan ko mọ nnkan to n jẹ iṣẹ ti ẹmi mimọ gbe le wa lọwọ. Mo gbọ pe awọn kan n sọ pe 'nitori wọn ko mu owo wa, lo jẹ ka sọ pe ki wọn maa lo.'

"A ni ki ẹ maa lọ nitori pe ẹ ko so eso rere! Ikuna nla. Ki lẹ wa n ṣe nibẹ? Awa ko ni suuru fun ikuna nibi rara.

"Nigba ti a gba awọn ẹgbẹrun meje lẹẹkan ṣoṣo, ẹrọ ayelujara ti ku bi? A ni awọn ti a gba siṣẹ ju pupọ awọn ipinlẹ lọ.

"Ko sẹni ti a jẹ lowo, ti a ko si yawo, bẹẹ la ko bẹbẹ fun owo. Ẹ lọ beere lọwọ awọn ile ifowopamọsi wa boya a jẹ wọn lowo. A duro lori majẹmu wa ni, ti a si n ṣiṣẹ fun imọlẹ Ọlọrun, ti a n gbadun ọrun to ṣi.

"Owo: RADARADA! Awa ko ṣaniyan owo, bẹẹ si la ko gbadura fun un, a ṣa kan n gbọran si Ọlọrun lẹnu, ti Ọlọrun si n ti wa lẹyin gbogbo ohun to n paṣẹ rẹ fun wa. Ọl'ọrun alagbara."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI