Inú mi kì í dùn nígbà tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mi bá ń ṣẹ - Wòlíì Ayọ̀délé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Saturday, July 17, 2021

Inú mi kì í dùn nígbà tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mi bá ń ṣẹ - Wòlíì Ayọ̀délé


Iru Wolii bi i alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual Church, Primate Elijah Babatunde Ayọdele ko wọpọ lorile-ede Naijiria, paapaa nilẹ Afrika. Ki i ṣe ti ẹnu tabi asọdun rara, nitori pe ṣaṣa ni asọtẹlẹ rẹ yi ki i wa si imuṣẹ lọpọlọpọ igba to ba sọ ọ jade. 

Kolonka lawọn asọtẹlẹ ti Wolii Elijah Ayọdele ti sọ, ti wọn si ti wa si imuṣẹ. Lara rẹ ni ti wahala ati rogbodiyan to n sẹlẹ lọwọlọwọ ni orile-ede South Africa. Oni ti i ṣe Abamẹta, Satide, lo pe ọsẹ kan gbako ti Wolii Ayọdele sọ asọtẹlẹ nipa nnkan to n sẹlẹ lọwọ naa, to si jẹ pe ko ju ọjọ mẹrin ti gbajumọ Wolii yii sọrọ jade, to di pe rogbodiyan bẹ silẹ nibẹ.

Ọpọlọpọ igba lawọn eeyan, paapaa awọn alaimọkan ti bu ẹnu atẹ lu Wolii Ayọdele nipa awọn asọtẹlẹ to maa n mu ijamba wa, sibẹ, ko fẹẹ si asọtẹlẹ kan ti Wolii ijọ INRI sọ jade, ti ki i sọ nipa awọn ọna abayọ rẹ.

Fun awọn to ba ni oye Ẹmi Mimọ, tabi imọ nipa bi Ọlọrun ṣe n fun awọn to gba a gbọ ni ẹbun asọtẹlẹ, wọn yoo mọ pe iru ẹbun ti alaṣẹ laye ati lọrun fun Wolii Ayọdele ko wọpọ rara. 

Bi Wolii Ayọdele ṣe n sọ asọtẹlẹ nipa ọrọ oṣelu, bẹẹ lo n sọ nipa eto ọrọ aje, okoowo, idagbasoke, agbo oṣere, ijọba orile-ede ati oniruuru ẹka lorilẹ aye yii, bẹẹ naa lo tun n sọ asọtẹlẹ nipa ere idaraya loriṣiriṣi. 

Bo ti sọ nipa ẹgbẹ agbabọọlu, bẹẹ naa lo n sọ nipa awọn agbabọọlu funra wọn, ti yoo si tun sọ bi idije ati ifigagbaga yoo ṣe lọ si.

Yatọ si eyi, ọdọọdun ni Wolii Ayọdele maa n gbe iwe asọtẹlẹ rẹ jade, fun awọn eeyan lati ni akọsilẹ awọn ohun to ba n sọ pe yoo sẹlẹ, pẹlu ọna abayọ wọn. Ọdun kẹtadinlọgbọn ree, ti Wolii Ayọdele ti n gbe iwe asọtẹlẹ rẹ to pe ni 'Warnings To The Nation' jade. 

Nigba to n sọrọ lori orukọ buruku tawọn eeyan ti pe e loriṣiriṣi nipa awọn asọtẹlẹ rẹ, Wolii Ayọdele ni oun ki i ṣe alasọtẹlẹ buruku, gẹgẹ bi awọn kan ṣe n ro. 

O jẹ ko ye gbogbo aye wi pe bi Ọlọrun ko ba fi iran han oun, ko ṣee koun sọ ọ jade, idi ree to fi loun maa n sọ awọn ọna abayọ lori asọtẹlẹ kọọkan.

Wolii Ayọdele ni ọpọ igba toun ba ri awọn asọtẹlẹ oun, ti wọn n wa si imuṣẹ, inu oun ki i dun si i, nitori pe awọn eeyan ki i kọbi ara si i. O ni bi awọn eeyan ba n kọbi ara si awọn asọtẹlẹ oun ni, ti wọn si n tẹle awọn amọran, pupọ awọn asọtẹlẹ naa ni ko ni i wa si imuṣẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI