Olugbo tilu Ugbo, ati olori ọba alaye nilu Ugbo, ipinlẹ Ondo, Alayeluwa Ọba Fredrick Ọbatẹru Akinruntan, Okoro Ajiga kin-in-ni tifi imọriri rẹ han lọwọ gbogbo awọn to ki i fun ti ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ laipẹ yii.
Kabiyesi loun ko le ṣai dupẹ lọwọ igbimọ awọn ọba lorileede yii, paapaa gbogbo ọba ilẹ Yoruba lapapọ, ijọba orile-ede yii ati awọn gomina patapata fun bi wọn ṣe yẹ oun si.
Ninu ọrọ idupẹ Kabiyesi siwaju si i lo ti sọ pe
Ẹsẹ Mo Dupẹ Pupọ.
A Ṣe Yi Ṣe Amọdun Ni Agbara Eledumare.
Ire Gbogbo A Maa Jẹ Ti Wa.
Ire Owo, Ire Ọmọ, Ire Alaafia, Ire Aiku A Jẹ Tiwa.
Mo Gba Adura Gẹgẹ Bi Olori Alaje Gbogbo Ilẹ Yoruba wipe Owo, Ọrọ ati Ibukun Ko Nii Han Wa.
Malokun Ogbolu A Gbe Ire Wa Fun Gbogbo Wa.
Ọsangangan Obamakin A Jẹ Ki A Ri Ti Aje Ṣe.
Ọranfẹ Onile Ina A Gbe Wa Si Ire Gbogbo.
Ilẹ Yoruba A Tuba A Tuṣẹ Lagbara Eledumare.
No comments:
Post a Comment