Kí lẹ mọ̀ nípa Ọláìyá Igwe, àgbà òṣèré tíátà tó ń ṣe ọjọ́ ìbí lónìí? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 27, 2021

Kí lẹ mọ̀ nípa Ọláìyá Igwe, àgbà òṣèré tíátà tó ń ṣe ọjọ́ ìbí lónìí?


Oni, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 2021 ni ayẹyẹ ọjọ ibi gbajugbaja agba oṣere tiata nni, Alaaji Lukman Ẹbun Oloyede, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Ẹbun Ọlaiya Igwe.
 
Ẹbun Ọlaiya ki i ṣaimọ foloko lagboole ere idaraya, ti a tun mọ si tiata. Latigba ti ojumọ si ti mọ lawọn ololufẹ ọkunrin naa to filuu Abẹokuta ṣe ibugbe ti n fi atẹjiṣẹ ikini loriṣiriṣi ranṣẹ si i.
 
Bawọn eeyan ṣe n ki i lori fesibuuku, bẹẹ lawọn mi in ki lori Insitagiraamu, tawọn mi in si n ki lawọn ibi ti wọn mọ pe wọn ti le fi idunnu wọn han si i.
 
Lara awọn fiimu tọ Ọlaiya Igwe di gbajugbaja ati alẹnulọrọ lawujọ oṣere tiata, tawọn eeyan ko si le gbagbe rẹ ni Iru Ẹṣin, Oṣuwọn, Abẹla Pupa, Ọlọlade Mista Money, Ọga ọlọpaa, Alaṣẹ Aye, Iku Lopin, Aye Olorogun, Ere Agbere,ati bẹẹbẹẹlọ

Ọmọ bibi ilu Kemta ni Oke-Ejigbo, Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ni ọkunrin naa.
 

Ile-ẹkọ alakọọbẹrẹ ti St. Jude, Abẹokuta lo lọ, o si tẹsiwaju ni ile-ẹkọ girama ti Premier. O tun lọ si ile-ẹkọ gbogboniṣe ti Moshood Abiola Polytechnic, nibi to ti kẹkọọ nipa iṣẹ iroyin ati igbohunsafẹfẹ, Mass Communication.

Ọlaiya bẹrẹ iṣẹ tiata laaarin ọdun 70s pẹlu ẹgbẹ oṣere Musbau Ṣhodimu Theater Orgnaization, ti wọn jọ ṣe ere ori itage nileeṣẹ tẹlifiṣan NTA.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI