Dàpọ̀ Abíọ́dún búra fáwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ tuntun l'Ógùn, bẹ́ẹ̀ ló tún gbà wọ́n lámọ̀ràn (Fọ́tò rẹpẹtẹ) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 27, 2021

Dàpọ̀ Abíọ́dún búra fáwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ tuntun l'Ógùn, bẹ́ẹ̀ ló tún gbà wọ́n lámọ̀ràn (Fọ́tò rẹpẹtẹ)


Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun lanaa, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii ti bura fun gbogbo awọn oludije to jawe olubori sawọn ipo alaga, igbakeji alaga ati kansẹlọ kaakiri ijọba ibilẹ ogun to wa nipinlẹ naa.
  
Opin ọsẹ to kọja ni eto idibo sawọn ipo kaakiri ijọba ibilẹ waye, niti ti ajọ eleto idibo ipinlẹ Ogun, OGSIEC ti kede gbogbo awọn oludije sipo  labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bi awọn  to jawe olubori.
 
Gbagede Arcade Ground, to wa ni Oke Mọsan, Abẹokuta ni eto ibura yii ti waye, nibi ti gbogbo awọn agbaagba nidi oṣelu, alẹnulọrọ lawujọ, to fi mọ awọn ọba alaye kaakiri ipinlẹ naa ti peju-pesẹ.

Abiọdun gba gbogbo wọn lamọran wi pe ki wọn jẹ olotitọ, ki wọn si sunmọ awọn eeyan wọn nijọba ibilẹ ti wọn ti dibo yan wọn, bẹẹ lo ni ki wọn ṣe ojuṣe wọn gẹgẹ bo ti tọ, ati bo ti yẹ.

Diẹ ree lara awọn fọto bi eto naa ṣe lọ si:
 
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI