Lẹ́yìn oṣù méjì tó ji ọ̀kadà gbé n'Ílọrin, ọwọ́ tẹ Taofeek lọ́jọ́ ọdún Iléyá - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 21, 2021

Lẹ́yìn oṣù méjì tó ji ọ̀kadà gbé n'Ílọrin, ọwọ́ tẹ Taofeek lọ́jọ́ ọdún Iléyá


'Ẹ ṣe mi jẹjẹ, ẹ ṣaanu mi, iṣẹ eṣu ni' lọrọ ẹbẹ ti wọn lo n jade lẹnu Saliu Taofeek, ti wọn loo ji ọkada ọlọkada gbe lọsu karun-un, ọdun yii, to si jẹ pe latigba naa lo ti na papa bora.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, wọn ni latigba ti Taofeek ti ji ọkada ọhun gbe lo ti juba ehoro, eyi to jẹ kawọn agbofinro maa wa kaakiri lati ri i mu.
 
Nigba tọwọ palaba rẹ maa segi, inu ọja igbalode kan to wa lagbegbe Taiwo niluu Ilọrin la gbọ pe wọn ti kofiri Taofeek nibi to ti n ra nnkan ọdun Ileya lọwọ.
 
Awọn kan ti wọn da a mọ la gbọ pe wọn ta ileeṣẹ  ẹṣọ alaabo Sifu Difẹnsi lolobo, ko to di pe wọn sare wa a mu, mọbẹ.
 
Nigba to n fidi iroyin ọhun mulẹ lonii, Ọjọru, Wẹside, alukoro ileeṣẹ Sifu Sifẹnsi nipinlẹ naa, Babawale Zaid Afọlabi, sọ pe lati oṣu karun-un, ọdun yii lawọn ti n wa Taofeek.
 
O lawọn tiẹ ti kede rẹ sita wi pe awọn ti n wa a, ṣugbọn to ni ọjọ ọdun Ileya gangan ni aṣiri rẹ ṣẹṣẹ tu si wọn lọwọ.
 
Bẹẹ lo tun fidi rẹ mulẹ wi pe awọn yoo foju rẹ ba ile-ẹjọ laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI