Nǹkan de! Wòlíì Ayọdele tún ju bọmbu àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ ní Nàìjíríà sílẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 21, 2021

Nǹkan de! Wòlíì Ayọdele tún ju bọmbu àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ ní Nàìjíríà sílẹ̀


Inu ibẹrubojo ati aibalẹ ọkan ni gbogbo awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lapapọ tun wa bayii, pẹlu bi alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Babatunde Elijah Ayọdele, tun ṣe ju bọmbu asọtẹlẹ nipa ọwọngogo ti yoo ba ounjẹ sita, o ni wọn yoo ta irẹsi lẹgbẹrun marundinlaadọta naira laipẹ.
 
Yatọ si pe Wolii Ayọdele sọ asọtẹlẹ nipa ohun ti yoo ṣẹlẹ lorilẹ-ede yii, bẹẹ lo tun mẹnuba awọn asọtẹlẹ tuntun ti yoo ṣẹlẹ lawọn orilẹ-ede kan nilẹ Afrika.

Wolii Ayọdele loun ri rogbodiyan ti yoo ṣẹlẹ lawọn ẹnubode orilẹ-ede kan nilẹ Afrika, eyi ti yoo yoo ṣakoba fawọn nnkan ti wọn n ko wọle.
 
O  ni owo irẹsi yoo kuro niye ti wọn n ta a, ti yoo si di ẹgbẹrun marundinlaadọta naira, iyẹn iye ti wọn yoo bẹrẹ si i ta a, nitori awọn wahala ti yoo ṣẹlẹ lẹnubode to so Naijiria ati ilẹ Benin papọ.
 
Ninu atẹjade to jade lati ẹka ileeṣẹ to n bojuto ọrọ iroyin rẹ la ti ri asọtẹlẹ naa gba.
 
O ni "Wahala ati rogbodiyan maa ṣẹlẹ lawọn ẹnubode awọn orilẹ-ede Afrika kọọkan, gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣe fi han mi. Naijiria ati Benin maa lawọn ipenija ti yoo koju adehun eto ọrọ aje to wa laaarin wọn, o maa nilo ki ajo ECOWAS da si i lati le yanju ẹ. Eyi yoo pa awọn nnkan tawọn eeyan n ra lara, ati pe owo irẹsi maa lọ soke si ẹgbẹrun marundinlaadọta naira.
 
"Ẹ jẹ kawọn ijọba orilẹ-ede mejeeji tete yanju aawọ to ba wa laaarin wọn, ko to o pẹ ju, ko ma ba a pa awọn araalu lara.
 
"Zambia, Burkina Faso, Burundi, Cameroun, Ivory Coast, Cape Verde, Mali, Kenya, Sudan ko ni gba ijageere eto ọrọ aje lawọn ẹnubode wọn laaye mọ. Wọn ni lati gbadura fun alaafia Ọlọrun lati jọba lawọn orilẹ-ede yii, mo ri wọn ninu wahala, idaamu ati rogbodiyan nla."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI