Olubadan tilẹ Ibadan lapapọ, Ọba Saliu Akanmu Adetunji, Aje Ogungunnisọ kin-ni-in ti gbe igbimọ agba nla nilẹ Ibadan dide lati lọ wo bi nnkan yoo ṣe lọ nile ẹjọ ilẹ Benin.
Bẹ o ba gbagbe, ọla, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn ni ẹjọ naa fẹẹ tẹsiwaju lati mọ boya wọn yoo fi Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho silẹ, tabi yoo ṣẹwọn lọdọ wọn.
Ninu atẹjade ti Adeọla Ọlọkọ to jẹ agbẹnusọ Olubadan lori ọrọ iroyin gbe jade lonii, lo ti fidi rẹ mulẹ wi pe igbimọ ọhun ti gbera.
Bo tilẹ jẹ pe ko sọ iru awọn to wa ninu igbimọ naa ṣugbọn ta a gbọ pe lara awọn agbaagba ilẹ Ibadan ati Yoruba lapapọ ni wọn. Awọn si ni wọn yoo lọ ṣoju Kabiyesi nibẹ.
Lẹyin ti kabiyesi pari ijororo pẹlu agbaabba ilu Ibadan (Central Council of Ibadan Indigenes) ti Aarẹ wọn, Ọmọọba Yẹmisi Adeaga; Ọmọwe Tirimisiyu Ọladimeji; Ẹkẹfa Olubadan, Oloye Agba Lekan Alabi; Ajia Olubadan, Oloye Wasiu Aderoju Alaadorin; Mọgaji Makusọta, Ọjọgbọn Oluwaṣẹgun Adekunle ati Ọgbẹni Adeọla Ọlọkọ.
Olubadan ninu ọrọ rẹ sọ pe lati le jẹ ko ye awọn ọmọ ati olugbe ilu Ibadan wi pe awọn ko pa Sunday Igboho ti lo jẹ ki wọn gbe igbesẹ.
Kabiyesi ni ọpọ awọn alatilẹyin Igboho ni wọn n fojoojumọ wa fi ẹhonu han laafin to wa ni Popoyemọja.
"Ilu Ibadan ni Sunday Igboho n gbe, Ibadan lo ti fẹ iyawo, Ibadan lo ti bi awọn ọmọ rẹ, Ibadan lo kọ ile si. Fun idi wọnyi, a ni lati daabo bo Igboho."
No comments:
Post a Comment