Sàlámì, agbẹjọ́rò Sunday Ìgbòho ṣe ìkìlọ̀ ńlá fáwọn olólùfẹ́ ọkùnrin naa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 25, 2021

Sàlámì, agbẹjọ́rò Sunday Ìgbòho ṣe ìkìlọ̀ ńlá fáwọn olólùfẹ́ ọkùnrin naa


Ọla, ọjọ Aje, Mọnde ni Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ ti awọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho atawọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye yoo mọ ibi ti wọn n lọ lori ọrọ olori ajijangbara ilẹ Yoruba yii.

Ibrahim David Salami to jẹ agbẹjọro Igboho ti sọ pe ki gbogbo awọn ololufẹ ọkunrin naa patapata jinna si ile ẹjọ ti igbẹjọ yoo ti waye niluu Cotonou, orilẹ-ede olominira Benin.

O ni iwa ti wọn hu lọsẹ to kọja yii ku diẹ kaato, iyẹn lasiko to n ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ

Salami ni "A maa pada si ile ẹjọ ni ọla, Mọnde. Bi a ba tẹle ilana ofin Benin, ile ẹjọ mi in ni yoo gbe ẹsun ti wọn fi kan an wo, nigba ti ile ẹjọ mi in yoo dajọ.

"Ki Mọnde to o pari, a maa mọ boya ijọba Benin yoo fi Sunday Igboho si ahamọ wọn tabi pe wọn yoo fi silẹ lati jẹ ko maa lọ. Ọjọ Mọnde la maa mọ.

"L'Ọjọbọ, Tọsidee to kọja, awọn ọmọ Yoruba ti wọn wa lati Naijiria ati awọn to n gbe ni Benin lo wa nile ẹjọ, eyi ko dara to.

"Ki wọn jokoo sile wọn, ki wọn ni suuru lati maa fi adura ran wa lọwọ. Ẹ jẹ ki awọn agbẹjọro ṣiṣẹ wọn. Ki wọn ma ṣe di wa lọwọ

"Bi wọn ba fẹsun kan ẹni ti wọn fẹsun kan wi pe o n di wọn lọwọ, ti awọn eeyan si n wa si kọọtu lati di wọn lọwọ, eyi ko le ran ẹjọ Igboho lọwọ. Ẹ jẹ ki gbogbo eeyan jokoo sile lati maa fi adura ran wa lọwọ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI