Ó mà ṣe o! Àgùnbánirọ̀ márùn-ún pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàmbá ọkọ̀ lọ́jọ́ kan ṣoṣo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, July 30, 2021

Ó mà ṣe o! Àgùnbánirọ̀ márùn-ún pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàmbá ọkọ̀ lọ́jọ́ kan ṣoṣo


Adura ti awọn eeyan maa n gba ni gbogbo igba wi pe 'Ki Ọlọrun ma jẹ ka rin lọjọ ti ebi n pa ọna' ko gba rara fun awọn agunbanirọ marun-un ti ẹ n wo yii, nitori bi wọn ṣe padanu ẹmi wọn sinu ijamba ọkọ lojiji.
 
Ohun to tubọ ṣe ni laaanu ni pe fasiti kan naa, iyẹn Fasiti tilu Uyo, ipinlẹ Akwa-Ibom lawọn maraarun-un ti ṣetan, ti wọn si n lọ si ibi ti wọn yoo ti sin orilẹ-ede baba wọn, iyẹn ilu Katsina ti wọn pin wọn si.

Ilu Abuja la gbọ pe wọn de, ko to di pe wọn pade iku ojiji yii. Ẹẹmarun-un ọtọọtọ la gbọ pe mọto ti wọn wọ gbokiti lori ere. Loju ẹsẹ lawọn marun-un yii ti dagbere faye, ti awọn yooku ti wọn jọ wa ninu mọto ọhun si farapa yannayanna.
 
Awọn ẹlẹyinju aanu ni iroyin fi to wa leti wi pe wọn doola ẹmi awọn ti ko ti i ku, pẹlu bi wọn ṣe sare ko wọn lọ si osibitu.

Mẹta ninu awọn agunbanirọ yii ni wọn pe ni Miracle Asuquo, Stella Ekikor ati Victor Akpan.

Adari ajọ agunbanirọ, ẹni to tun jẹ gẹgẹ bi alukoro, Adenikẹ Adeyẹmi, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe ijẹta ti i ṣe Ọjọru, Wẹsidee lawọn eeyan naa kagbako ijamba ọkọ yii lopopona marosẹ Abaji si Kwali, ni nnkan bi aago meji oru.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI