Ọ̀rọ̀ burúkú tòun tẹ̀rín! Ẹ wo Eégún tó ń wàásù ìhìnrere Jésù láàárín ọjà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, July 30, 2021

Ọ̀rọ̀ burúkú tòun tẹ̀rín! Ẹ wo Eégún tó ń wàásù ìhìnrere Jésù láàárín ọjà


Ọrọ buruku nla toun tẹrin gba a lọrọ Eegun kan to ṣa deede wọnu ọja lọsan gangan, to si n waasu ihinrere Jeesu fawọn eeyan nibẹ.
 
Ninu fọnran to tẹ wa lọwọ, nibi ti Eegun naa ti n waasu lo ti sọ pe ki gbogbo eeyan yi pada kuro ninu ẹṣẹ wọn, ki wọn si sa wa sọdọ Jesu fun igbala ẹmi wọn.
 
Ki i ṣe pe Eegun yii mu ọrọ iwaasu rẹ ni kekere rara, o tun gbe ẹrọ gbohungbohun {Megaphone} dani, eyi to fi n pariwo si eti awọn eeyan wi pe ijọba ọrun ku si dẹdẹ.


Ilẹ Ibo lọhun ni iṣẹlẹ yii ti waye, gẹgẹ bi fọnran naa to tẹ wa lọwọ ṣe fi han nibẹ, nitori pe ẹdẹ Ibo pọmbele ni Eegun yii fi n waasu, ki awọn eeyan le gbọ ohun to n sọ daadaa.
 
Bawọn eeyan ṣe ri Eegun yii, o jẹ iyalẹnu fun wọn, eyi to jẹ ki pupọ awọn to wa nibẹ gbe foonu lati ya aworan rẹ, ti wọn si fi ranṣẹ si AWIKONKO.

Fọnran naa ree:


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI