Ó mà ṣe o! Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Rachel Oniga kú lójijì - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 31, 2021

Ó mà ṣe o! Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Rachel Oniga kú lójijì


Bo tilẹ jẹ pe titi dasiko ta a pari iroyin yii ni a ko ti i le fidi iku to pa gbajugba agba oṣerebinrin nni, Rachel Tabuno Oniga mulẹ, ṣugbọn ta a gbọ pe alẹ ana, ọjọ Ẹti, Furaidee lo jade laye.

Ẹni ọdun mẹrinlelọgọta ni agbara oṣerebinrin to kọ ọkọ rẹ silẹ lọdun mọkandinlogun sẹyin.

A gbọ pe lati ibere ọsẹ yii ni oṣerebinrin naa fi wa niluu Mowe, ipinlẹ Ogun nibi to ti lọọ ṣiṣẹ ere fiimu kan ti wọn n popọ lọwọ.

Gbogbo awọn ollufẹ iṣẹ tiata, paapaa awọn oṣere tiata ni wọn ti n banujẹ gidi lori iku obinrin naa.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe arun korona, COVID-19 lo ṣeku pa obinrin naa.
 
Ọjọ kẹtalelogun, oṣu karun-un, ọdun 0957 ni wọn bi Rachel Oniga. Ọmọ ijọba ibilẹ Ethiope nipinlẹ Delta ni.
 
Ẹkunrẹrẹ iroyin naa n bọ laipẹ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI