Ó tán o! Nítorí àìṣe-déédéé, wọ́n fẹ́ẹ́ yọ adarí ẹgbẹ́ VGN danù l'Ógùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Saturday, July 31, 2021

Ó tán o! Nítorí àìṣe-déédéé, wọ́n fẹ́ẹ́ yọ adarí ẹgbẹ́ VGN danù l'Ógùn


Ẹni ta a fi joye awodi ti ko lee gbe adiẹ lọrọ adari ẹgbẹ eleto aabo fijilante, Vigilante Group of Nigeria, nipinlẹ Ogun, Ọmọọba Temitọpẹ Odogun fẹẹ jẹ bayii, pẹlu bi wọn ṣe lawọn adari ẹgbẹ naa ṣe sọ pe afi ko fi ipo silẹ ni dandan, nitori ti ko ṣe awọn nnkan ti wọn n reti lati ọwọ ẹ.
 
Wọn ni lati bi oṣu mẹta le diẹ sẹyin ni wọn ko ti gburo rẹ lati maa ṣe awọn ẹtọ rẹ ninu ẹgbẹ yii, eyi ti wọn ni ko bojumu to.
 
Bẹ o ba gbagbe, Ọgbeni Nureni Ọlanrewaju Adedoyin ni adari ẹgbẹ naa tẹlẹ, ko to di pe o gba igbega si ipo alukoro ẹgbẹ naa lapapọ.

Nibi ipade awọn oniroyin ti wọn ṣe lọjọ Ẹti, Furaidee ana ni wọn ti ṣalaye wi pe ṣe ni Odogun n mu ifasẹyin ba wọn ninu ẹgbẹ naa, nitori bi ko ṣe rin awọn irin to yẹ ko rin, eyi ti yoo mu ki itẹsiwaju ba wọn.

Eyi lo jẹ ki wọn dibo wi pe awọn ko fẹẹ mọ {vote of no confidence}.
 
Lẹta ti wọn gbe jade naa ree, ati awọn ti wọn tọwọ bọwe:No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI