Ọdún Iléyá! Ganduje tú ẹlẹ́wọ̀n 136 sílẹ̀, ó tún fún wọn lẹ́gbẹ̀rún márùn-ún náírà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 21, 2021

Ọdún Iléyá! Ganduje tú ẹlẹ́wọ̀n 136 sílẹ̀, ó tún fún wọn lẹ́gbẹ̀rún márùn-ún náírà


Gomina Abdullahi Umar Ganduje tipinlẹ Kano ti tu awọn ẹlẹwọn ti ko din ni mẹrindinlogoje (136) kaakiri ipinlẹ naa silẹ lanaa, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ti i ṣe ọdun Ileya.

Yatọ si pe Gomina Ganduje tu awọn ẹlẹwọn yii silẹ, wọn loo tun fun ẹnikọọkan lẹgbẹrun marun-un naira lati fi wọ mọto pada sile wọn.

Nibẹ lo ti gba wọn lamọran pe ki wọn gbe iwa ọmọluabi hu, bi wọn ba de awujọ, ati pe ki wọn lo anfaani awọn ẹkọ ti wọn ri kọ lakooko ti wọn wa lẹwọn lati maa fi gbawọn eeyan lamọran wi pe iwa ọdaran ko dara.

Lakooko to ṣe abẹwo si ọgba ẹwọn Gorondutse Medium ni Gomina gbe igbesẹ yii.

“Ipo ti ẹ wa gẹgẹ bi ọmọ Naijiria to nilo lati gba itọju, awa nibi lonii, ọjọ ọdun Ileya, lati ba a yin yọ, nipa fifi awọn ti wọn ri idariji gba silẹ.

“A tun wa nibi bakan naa lati ri i pe ẹ n gbadun ara yin, ka si lo anfaani asiko yii lati yọ pẹlu yin. A fẹ ki ẹyin ti ẹ ti yi iwa pada ṣe ileri wi pe ẹ ko ni i pada sinu iwa ibajẹ to gbe e yin debi mọ.”

Nigba to n ṣalaye idi to fi gbe igbesẹ naa, o sọ pe
“Ninu ẹyin ti a fi silẹ yii lo jẹ pe nitori ailera yin, awọn kan lo akooko wọn kọja, bẹẹ lawọn kan ṣi wa nibi nitori ti wọn ko ri owo ti wọn n beere lọwọ wọn san lasiko.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI