Ọpẹ́ o! Ọọ̀ni Ìfẹ, Ọba Adéyẹyè gbé ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni méjìdínlọ́gbọ̀n dìde láti dá sí ọ̀rọ Sunday Igboho - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Thursday, July 22, 2021

Ọpẹ́ o! Ọọ̀ni Ìfẹ, Ọba Adéyẹyè gbé ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni méjìdínlọ́gbọ̀n dìde láti dá sí ọ̀rọ Sunday Igboho


Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọọni Ile-Ifẹ ti gbe igbimọ agba ilẹ Yoruba ẹlẹni mẹjidinlọgbọn dide lati da si ọrọ wahala to n ṣẹlẹ si Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho.

A gbọ pe igbimọ naa yoo jiroro lori bi wọn yoo ṣe tu Igboho silẹ lahamọ to wa lorilẹ-ede olominira Benin, ati awọn ẹsun mi in ti wọn fi kan an.

Ẹni ti wọn yan lati dari igbimọ naa ni Ọjọgbọn Akin Ọṣuntokun.

Awọn mi in ninu igbimọ yii ni Ọba Oluṣọla Alao, Olugbọn tilu Igbọn, Sẹnnetọ Biọdun Olujimi, Toyin Saraki, Ṣẹgun Awolọwọ, Doyin Okupe, Oloye Gbenga Daniel ati Ọgbẹni Muyiwa Ige.

Ọkan lara awọn to sunmọ aafin Ọọni lo fi idi rẹ mulẹ laarọ oni, Tọsidee wi pe iṣẹ ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ.

Ẹni naa sọ pe wọn ti gbe igbimọ yii dide tipẹ, ati pe o ti le loṣu kan gbako, ṣugbọn to jẹ pe asiko ti wọn fẹẹ fi igbimọ naa lelẹ ni wahala de ba Igboho

1 comment:

  1. Ti iro balo fun ogun odun otito bowa bao orile ede Nigiria papa yoruba lapapo eso ododo ki a ma ba ri ibinu awon irumole ati awon orisa tori wipe iyan ogun odun olejoni lowo ooo i fi oloye Sunday adeyemo igboho le bi eba ko ti e o fi sile alajobi o ni jeki ile yoruba roru mo.

    ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI