Tinubu àti Yahaya Bello ló yẹ kó jẹ́ ẹ̀fọ́rí fún PDP, kìí ṣe Buhari - Ṣẹgun Ṣowunmi ju bọmbu ọ̀rọ̀ síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 22, 2021

Tinubu àti Yahaya Bello ló yẹ kó jẹ́ ẹ̀fọ́rí fún PDP, kìí ṣe Buhari - Ṣẹgun Ṣowunmi ju bọmbu ọ̀rọ̀ síta


Agbẹnusọ fun ẹgbẹ ipolongo idibo fun oludije sipo aarẹ orilẹ-ede yii, (Atiku Campaign Organisation), Ṣẹgun Ṣowunmi, ti sọ pe ki i ṣe ọrọ Aarẹ Muhammadu Buhari lo yẹ ko jẹ iṣoro fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ninu idibo apapọ to n bọ lọdun 2023, bi ko ṣe ọrọ awọn agba oṣelu meji kan lorilẹ-ede yii.
 
Ṣẹgun Ṣowunmi sọ pe Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu, ati gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello lo yẹ ko jẹ ẹfọri fẹgbẹ oṣelu PDP, ti wọn si gbọdọ ṣiṣẹ lori ẹ gidigidi.
 
Ori eto 'Politics Today', to maa n waye lori amohunmaworan ti Channels ni Ṣẹgun Ṣowunmi ti sọrọ naa jade laipẹ yii.
 
Nibẹ lo ti sọ pe ki i ṣe bawọn eeyan ṣe n lero wi pe Aarẹ Muhammadu Buhari ni yoo jẹ ẹfọri fun ẹgbẹ alatako ọhun ninu idibo ọdun 2023 lo ṣe ri rara.
 
Bakan naa lo tun sọ pe Buhari ko le jẹ oludije to yọranti ninu idibo eyikeyi lai ni atilẹyin Tinubu.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe:
"Awọn meji kan wa ninu ẹgbẹ oṣelu APC to n ko ẹfọri ba mi. Mo maa n ronu nipa Gomina Yahaya Bello, nitori awọn ipasẹ to n tọ ti mo ri, oun ṣi kere daadaa, to si le ba awọn eeyan gidi sọrọ. Bakan naa ni mo tun n ronu nipa Bọla Ahmẹd Tinubu, nitori pe mo mọ iru idagbasoke to ni lẹka oṣelu, nipa awọn iṣẹ to ti ṣe silẹ.
 
Siwaju si i lo tun jẹ ko di mimọ pe Buhari ko le bori aarẹ ana, Goodluck Jonathan ati igbakeji aarẹ tẹlẹri, Atiku Abubakar, ninu idibo ọdun 2015 ati 2019 lai ni atilẹyin Tinubu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI