Ọwọ́ tẹ Ọbásanjọ́ ati Awólọ́wọ̀ tó ń ṣiṣẹ́ ajínigbé ni Imo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 21, 2021

Ọwọ́ tẹ Ọbásanjọ́ ati Awólọ́wọ̀ tó ń ṣiṣẹ́ ajínigbé ni Imo


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo ti tẹ awọn gendekunrin mẹrin kan, pẹlu ọdọmọbinrin meji lori ẹsun ijinigbe ti wọn fi kan wọn. Iṣẹ naa la gbọ pe wọn n ṣe jẹun, ti wọn si n jaye ko kan mi kaakiri igboro.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Michael Abattam, nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe ọjọ kẹta, ọsu yii ni obinrin kan, Cornelia Oluebube to n gbe niluu Amakohia, ijọba ibilẹ Owerri North, lawọn eeyan yii jigbe, ti wọn si gbe e lọ si ahamọ wọn.
 
O ni bi iroyin naa ṣe tẹ ileeṣẹ wọn lọwọ, lawọn ti bẹrẹ iṣẹ ofintoto wọn. Lẹyin iwadii wọn lo sọ pe awọn gburo wọn sipinlẹ Delta, to si lawọn tọpinpin wọn lọ sibẹ.
 
Ko pẹ rara to fi sọ pe ọwọ tẹ gbogbo wọn, Terry's Mez, ọmọ ọdun mọkanlelọgbọn lati ilu Aguleri, nipinlẹ Anambra State; Willine Ebefal, ọmọ ọdun mọkanlelogun lati ilu Ogbokuno, ijọba ibilẹ Burutu, ipinlẹ Delta; Ọbasanjọ Kimakia, ọmọ ogun ọdun lati ilu Tamime, ijọba ibilẹ Burutu, ipinlẹ Delta.

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu yii, iyẹn ọjọ Aje, Mọnde lo sọ pe ọwọ tẹ wọn, ni nnkan bi aago mọkanla aabọ aarọ, to si lawọn gba ẹni ti wọn ji gbe silẹ lọwọ wọn lai farapa.


Awọn mi in tọwọ tun tẹ ni Augustine Irishaye, ọmọ ọdun mọkanlelogun; Jenifer Awolọwọ, ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn ati Eyemgblausi Chugbwugburefa, ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn. 
 
Agbegbe Den to wa ni Tebegbe Water Side, ipinlẹ Delta lo sọ pe ọwọ ti tẹ gbogbo wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI