Alikali, kọmíṣánnà lábẹ́ ìṣàkóso Fatai ní Kwara f'ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lọ APC lónìí - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Wednesday, July 21, 2021

Alikali, kọmíṣánnà lábẹ́ ìṣàkóso Fatai ní Kwara f'ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lọ APC lónìí


Yajoyajo niroyin yii n ṣẹlẹ lọwọlọwọ, pẹlu bi kọmiṣanna tẹlẹri fọrọ ipese omi nipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso gomina ana, AbdulFatah Ahmẹd, iyẹn Alaaji Yusuf Alikali ti kede sita gbangba wi pe oun ko ṣẹgbẹ oṣelu alatako, Peoples Democratic Party, PDP mọ.
 
O ti kede bayii wi pe ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC loun n ba lọ bayii, nitori pe awọn ilana idagbasoke wọn n wu oun lori gidi. Oni, Ọjọru, Wẹsidee lo darapọ mọ APC.
 
Alikali sọ pe irinṣẹ ni ẹgbẹ oṣelu PDP jẹ bayii nipinlẹ Kwara lati maa ba ẹgbẹ oṣelu APC lorukọ jẹ nipinlẹ naa, to si loun ko ṣe mọ, gẹgẹ ba a ṣe gbọ.
 
Nigba to n fi erongba rẹ lori bo ṣe lọ darapọ APC han ni wọọdu idibo rẹ to wa ni Magaji-Ngeri, ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ilọrin gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq nipa bo ṣe duro lori otitọ awọn ileri rẹ lakooko ipolongo idibo to gbe e wọle.
 
O ni ko si ariyanjiyan wi pe AbdulRazaq n fi otitọ mu awọn ileri rẹ ṣẹ, eyi to lo fa a toun naa fi pinnu lati lọ darapọ mọ ọn fun itẹsiwaju. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI