Panpẹ Aye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Thursday, July 29, 2021

Panpẹ Aye


Bi a ba n sọrọ nipa PANPẸ AYE, o jẹ nnkan pataki ti aye fi n mu ọmọ ologo. Panpẹ Aye ta a n sọrọ nipa rẹ yii, ko s’ẹni ti aye ko le dẹ ẹ silẹ fun. Wọn fi n mu Aafa, Pasitọ, Obinrin, Ọkunrin ati bẹẹ bẹẹ lọ. Panpẹ Aye le mu ọlọla tabi ọlọrọ.

Bi aye ba dẹ panpẹ wọn silẹ, ṣe ni wọn yoo da iyẹẹpẹ bo o, ti wọn yoo wa lọ duro s’oke lati maa ṣọ ohun ti pakute ti wọn dẹ silẹ yii yoo mu. Aye le dẹ panpẹ silẹ fun obinrin nile ọkọ, wọn le dẹ panpẹ silẹ sinu irin ajo aye eeyan ati nibi iṣẹ, bẹẹ ni ọmọọṣẹ le dẹ panpẹ silẹ fun ọga, ti ọga naa yoo tun dẹ panpẹ silẹ fun ọmọọṣẹ.

Panpẹ ni wọn fi mu ọpọ obinrin mi in to fi bọ sinu adanwo aye nipa agbere ṣiṣe kaakiri. Airọmọ bi ni panpẹ ti wọn dẹ silẹ fun ẹlomi in nile ọkọ, koda to jẹ pe ile ọmọ obinrin mi in ni aye ti gbọwọ le. Ṣe ni awọn to bọ sinu panpẹ yii yoo wa maa na owo, ti wọn yoo maa nọra, ti yoo tun maa ta ile ati ọna lati fi wa ojutuu, ṣugbọn ti wọn ni i bọ ninu panpẹ ọhun.

Nibi iṣẹ ẹlomi in, ẹni to n gba ilẹ le dẹ panpẹ silẹ fun ọga ileeṣẹ, ti wọn yoo ni ko kẹ panpẹ naa silẹ si ori aga fun ọga ileeṣẹ, ti ọga naa yoo si jokoo le e lori lai ranti pe, panṣa ko fura, panṣa ja sina; aja ko fura, aja jin... Nibẹ ni ọga ileeṣẹ yoo ti rọ lọwọ-rọ lẹsẹ. Pakute aye ti mi un!

PANPẸ AYE yii ko ni i mu mi, ko ni i mu ẹyin ti ẹ n ri ọrọ mi yii ka ati arọmọdọmọ yin lagbara Ọlọrun. Iya ẹlomi in ni PANPẸ AYE rẹ nitori ninu iwadii laa ti ri i pe, gbogbo obi kọ ni yoo jẹun ọmọ, ṣugbọn mo gba a l’adura fun gbogbo abiyamọ aye pe, ounjẹ ọmọ ko ni i koro l’ẹnu gbogbo wa. Amin.

Nitori naa, ki gbogbo abiyamọ gbe ile aye ṣe rere nitori ọpọ obi lo ti lo igba ọmọ wọn mọ igba ti wọn, paapaa lasiko ti wọn n wa agbara aye kaakiri. Ọpọ ọmọbinrin lo ti pe ogoji ọdun lọ soke ti wọn ko ri ọkọ fẹ. PANPẸ AYE lo ti mu iru ọmọ bẹẹ nipasẹ awọn obi rẹ nitori ọpọ obi lo ti fi ọmọ wọn lelẹ n’igba ti oju n pọn wọn.

Abajọ ti Bibeli fi ni ‘a o bẹ ẹṣẹ baba wọ lara ọmọ’. Ninu irin-ajo ẹlomi in lo ti jẹ pe, irin ti awọn obi wọn rin ni wọn ti fi awọn at’awọn arọmọdọmọ sinu panpẹ aye. Ọpọ lo jẹ pe, o ni iye ọjọ ori ti wọn ko gbọdọ kọja ninu ẹbi wọn. PANPẸ AYE yii ni ki i jẹ ki ọmọ ologo ri ogo rẹ lo. Takute aye ko ni i mu gbogbo wa o.

O ṣeni laaanu pe, ọpọ lo ti gbagbe iṣẹṣe ati iṣẹmbaye nitori o yẹ ki eeyan wadii nitori aiwadii lo jẹ ki ọpọ ọmọ ologo wọnu idile mi in ti ogo wọn ti wọmi lati fẹ ọkọ tabi aya. PANPẸ AYE jẹ ohun ibanujẹ nitori ipayinkeke ni fun ẹni to ba ti mu.

Ṣe panpẹ airọmọ bi, ai ri ọkọ tabi aya fẹ, aisan rọpa-rọsẹ, igbega ti o n le, ilu oyinbo ti wọn ti n le ọ pada ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn dẹ fun iwọ?

PANPẸ AYE maa n mu ni dọjọ iku bu, ṣugbọn ọlọdẹ kan wa ti Olodumare ti yan silẹ lati maa yọ panpẹ kuro lẹsẹ gbogbo ẹni ti aye ba dẹ panpẹ fun. Nibikibi ti o ba wa ti aye ti n fi panpe mu ẹ, gbera ki o maa bọ lọdọ Baba Egun Aworawọ, ẹni ti Olodumare fi n yọ eeyan kuro ninu PANPẸ AYE ati Egun Aye l’asiko yii.

Mo gbadura pe, a ko ni i ṣirin lọjọ ti aye ba dẹ panpẹ silẹ o. Nitori naa, nibi ti iwọ naa ba n ro lọkan tabi foye gbe e pe o ti bọ sinu PANPẸ AYE, tete maa bọ lọdọ Baba Egun Aworawọ. Mo gbadura pe Naijiria ko ni i bajẹ o.

Baba Egun Aworawọ

Tete kan si Baba Egun Aworawọ ni ọfiisi wọn, bẹẹ ni awọn iṣẹ ajẹbiidan oriṣiriṣi lati ọwọ Baba ṣi wa nilẹ. Ẹ ma ṣe gbagbe pe lati foju kan Baba Egun Aworawọ, ẹ maa gba fọọmu ẹgbẹrun meji (N2,000) naira pere. Ẹ si le pe Baba sori: 07038302541, tabi ki ẹ kan si wọn lori wasaapu wọn,
09022671569.
 
Bi ẹ ba fẹẹ ra eyikeyi awọn ọja Baba Egun Aworawo, ẹ pe awọn nọmba yii: 07040508855 ati 08165703400. Ileeṣẹ Baba Egun Aworawọ wa ni Doyin Bus-Stupo, Off Agbara/Lusada Road, Ogun State.
 
Ko si irufẹ aajo ti ẹda fi n jẹ eeyan laye ti ẹ wa de ile itaja Baba Egun Aworawọ, ti ẹ ko ni ba nibẹ, to si jẹ pe bi ẹ ba ẹe n lo wọn, lẹsẹkẹsẹ lẹ o ti maa jẹri si agbara Olodumare.

Ẹyin eniyan, gẹgẹ bi a ti ṣe mọ wi pe baba Egun Aworawọ jẹ gbajugbaja oniṣegun ti gbogbo aye n wari fun lasiko ta a wa nisinyi, awọn aajo ọla ti n jẹ ki ẹda ni aje ogungunisọ, awọn akanṣe iṣẹ pataki wọnyii ti wa nilẹ babi ninu ile itaja wa, ti a si n ta ọkọọkan ninu rẹ ni ẹgbẹrun marun-un aabọ {N5,500} naira pere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI