Wọ́n ju Oyinlọlá, gbajúmọ̀ Ọmọọba Ọ̀ṣun ṣẹ́wọ̀n oṣù mẹ́ta n'Ílọrin lórí ẹ̀sun 'Yahoo-Yahoo' - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 29, 2021

Wọ́n ju Oyinlọlá, gbajúmọ̀ Ọmọọba Ọ̀ṣun ṣẹ́wọ̀n oṣù mẹ́ta n'Ílọrin lórí ẹ̀sun 'Yahoo-Yahoo'


Ile-ẹjọ giga tipinlẹ Kwara, eyi to wa niluu Ilọrin lanaa, Ọjọru, Wẹsidee, ti ju
ọkan lara awọn Ọmọọba nipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Oynlọla Adedayọ Emmanuel sẹwọn oṣu mẹta gbakolori ẹsun jibiti ori ayelujara, iyẹn Yahoo-Yahoo ti wọn fi kan an.

Yatọ si Ọmọba Oyinlọla, ile-ẹjọ tun ju awọn meji mi in, Owonikoko Kẹhinde Damilare, to jẹ akẹkọọ fasiti ilu Ilọrin ati Jimọh Akeem Lawal sẹwọn lori ẹsun ọtọọtọ to ni i ṣe pẹlu jibiti ti wọn fi kan wọn.

Oyinlọla, ọmọ ọdun mejidinlọgbọn to pe ara rẹ ni Ọmọọba nijọba ibilẹ Odo-Otin, ipinlẹ Ọṣun la gbọ pe yoo fi ẹwọn oṣu mẹta naa gbara lai san owo itanran kankan lati rọpo ẹwọn rẹ.
 
AWIKONKO gbọ pe Oyinlọla gba wi pe loootọ loun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an niwaju Onidajọ Mahmood Abdulgafar ti ile-ẹjọ naa.
 
Bẹẹ ni yoo tun gbagbe ẹrọ kọmputa alagbeeka ati foonu ti wọn gba lọwọ ẹ sọwọ ijọba orilẹ-ede Naijiria.
 
Ẹsun mẹrin ọtọọtọ la gbọ pe wọn fi kan Jimọh Akeem niwaju Onidajọ Abdulgafar, to si ju oun sẹwọn ọdun kan gbako lori ẹsun kin-in-ni, ekeji ati ẹkẹta; ẹwọn oṣu mẹfa gbako lori ẹsun kẹrin lai san owo itanran lati rọpo ẹwọn ohun naa.
 
Bẹẹ ni Onidajọ Abdugafar paṣẹ pe gbogbo ẹru ti wọn gba lọwọ ẹ bi i foonu, ẹrọ kọmputa alagbeeka, to fi mọ owo rẹ nile ifowopamọ ni ki wọn gba fun ijọba orilẹ-ede yii.
 
Ni ti Owonikoko, Onidajọ Sikiru Oyinloye paṣẹ pe koun lọọ fi ẹwọn oṣu mẹfa gbako gbara lori ẹsun kin-in-ni, tabi ko san ẹgbẹrun lọna aadọta naira gẹgẹ bi owo itanran; ati ẹwọn ọdun gbako lori ẹsun keji ti wọn fi kan an lori ẹsun keji tabi ko san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira gẹgẹ bi owo itanran, bi ko ba fẹẹ lọ sẹwọn
 
Onidajọ Oyinloye sọ pe iPhone ati ẹrọ kọmputa alagbeeka ti wọn gba lọwọ ẹ, to fi mọ ẹgbẹrun mejidinlaadọfa ataabọ (N112,500) naira ni ki wọn ko sapo ijọba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI