Wàhálà tuntun dé bá Saraki - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 31, 2021

Wàhálà tuntun dé bá Saraki


Lonii ọjọ Satide, Abamẹta ni ajọ o n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorilẹ-ede yii, Economic and Financial Crimes Commission wọ Aarẹ ilẹ igbimọ aṣofin ana, Bukọla Saraki gbuurugbu lori ẹsun iwa jibiti ati ajẹbanu ti wọn fi kan an.
 
Titi di asiko ti a pari iroyin yii laago meje kọja iṣẹju mẹwaa irọlẹ la gbọ pe Bukọla Saraki ṣi wa lahamọ ajọ EFCC, nibi ti wọn ti n fi ọrọ wa a lẹnu wo lori awọn dukia ti wọn loo fọna eru ko jọ.
Lati aarọ la gbọ pe Saraki ti wa lọdọ awọn EFCC.

Saraki ni Aarẹ ile igbimọ aṣofin orilẹ-ede yii laaarin ọdun 2015 si 2019, bẹẹ lo tun ti figba kan ri jẹ gomina ipinlẹ Kwara ko to o dije du ipo Sẹnetọ.
 
Wahala tuntun to de ba Saraki yii la gbọ pe o ṣee ṣe ko ṣakoba fun un lẹka eto oṣelu lorilẹ-ede Naijiria.

Gbogbo asiko ti Saraki fi wa lori ipo Sẹnetọ la gbọ pe o fi n jẹjọ lori ẹsun kiko dukia jọ lọna jibiti, ṣugbọn ti ilẹ ẹjọ agba orilẹ-ede yii pada da a lare loṣu kẹfa, ọdun 2018.

A gbọ pe lara awọn ibeere ti wọn ni Saraki maa dahun lọdọ ajọ EFCC ni bo ṣe ṣe owo araalu lakooko to wa nijọba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI