Alakoso banki dero ẹwọn ọdun marun-un lori ẹsun jibiti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, August 12, 2021

Alakoso banki dero ẹwọn ọdun marun-un lori ẹsun jibiti


Oniadajọ M. M. Abubakar tile ẹjọ giga ipinlẹ Bauchi ti ju obinrin kan Sarita Aliyu Bello, to jẹ alakoso banki ẹyawo nni, iyẹn Workman Microfinance Bank, to wa nipinlẹ ọhun sẹwọn ọdun marun-un gbako pẹlu iṣẹ aṣekara lori ẹsun jibiti ti wọn fi kan an.
 
Ileeṣẹ to n gun ti ṣiṣẹ owo ilu kumọkumọ ati iwa jibiti lorilẹ-ede Naijiria, Econimic and Financial Crimes Commission {EFCC} ni wọ fẹsun meji ọtọọtọ kan Bello wi pe o kowo banki ẹyawo naa jẹ.

Esun ti wọn fi kan an naa lo nii ṣe pẹlu yiyi iwe ati ṣiṣẹ owo kumọkumọ, eyi ti wọn lo tako iwe ofin ti iwa jibiti labala ọọdunrun le ni mẹjọ {
308} ati mẹtalelọgọta le ni ọọdunrun {363}, eyi to ni ijiya ninu.
 
Odun 2020 to kọja la gbọ pe owo to din diẹ ni miliọnu marun-un naira {N4,786,700} lo poora labẹ iṣakoso Bello, ti wọn ko si ri akọsilẹ rẹ ṣe lẹkunrẹrẹ.

Wọn ni ṣe lo lo ọgbọn alumọkọyi lati gbe ẹyawo jade lorukọ alakoso ileeṣẹ naa to n gbe owo jade {Head of Credit Unit} pẹlu ayederu orukọ, to si jẹ pe apo ara rẹ ni owo ọhun lọ.
 
Bi wọn ṣe ṣakiyesi eyi la gbọ pe wọn ti ranṣẹ sawọn EFCC lati ran wọn lọwọ nipa iwadii, ti wọn si gbe Bello.
 
Ile-ẹjọ ni Bello ti sọ pe loootọ loun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun, ṣugbọn iṣẹ eṣu ni, ati pe oun ko tun ni ṣe iru ẹ mọ, bi wọn ba le foun lanfaani lati maa lọ layọ ati alaafia.

Onidajọ Abubakar wa a sọ pe ki Bello lọ fi ẹwọn ọdun marun-un gbara, bẹẹ si ni ko da gbogbo owo to ji ko pada fun banki ẹyawo to ti n ṣiṣẹ nipasẹ EFCC.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI