Orọ bẹyin yọ! Ile-ẹjọ paṣẹ fun Mukaila Akinwande lati yee pe ara rẹ ni Oluwo Ijẹja l'Abẹokuta mọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Tuesday, August 10, 2021

Orọ bẹyin yọ! Ile-ẹjọ paṣẹ fun Mukaila Akinwande lati yee pe ara rẹ ni Oluwo Ijẹja l'Abẹokuta mọ


Lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni ile-ẹjọ giga tipinlẹ Ogun to wa ladugbo Iṣabọ niluu Abẹokuta paṣẹ fun ọkunrin kan to pe ara rẹ ni Mukaila Akinwande lati yee pe ara rẹ ni Oluwo ilu Ijẹja mọ, bi bẹẹ kọ, o ṣee ṣe ko fi ẹwọn jura.
 
Onidajọ Ogunfowora lo gbe idajọ naa kalẹ lonii wi pe titi digba ti igbẹjọ mi in yoo fi waye laaarin ọsẹ meji si akooko yii, ọkunrin naa ko gbọdọ jade sita lati fi ara rẹ han wi pe oun ni Oluwo ilu Ijẹja.
 
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Oloye Arẹmu Bamgboye ti ọpọ awọn eeyan mọ si Ajiki-Olu lo gbe ẹjọ lọ si kọọtu loṣu keji, ọdun yii, wi pe awọn kan fẹẹ gba ipo ti Alake ilẹ Egba, Oba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ foun jẹ lọwọ oun, ti wọn si fẹẹ gbe fun ẹlomi in, iyẹn Mukaila Akinwande.
 
Nigba to n gbe idajọ naa kalẹ lonii, Onidajọ Ogunfowora sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun ko ni i da ojulowo ẹjọ lonii, bi ko ṣe pe koun ṣi sọ fun Mukaila Akinwande lati dẹkun nipa pipe ara rẹ ni Oluwo ilu Ijẹja mọ.
 
Saaju akooko yii, gẹgẹ ba a ṣe gbọ, agbẹjọro Ogbẹni Akinwande, Ogbẹni Apaniṣile sọ pe oun nilo aaye diẹ lati gbe ẹjọ naa yẹwo daadaa, koun si le mọ boun yoo ṣe gbeja onibara oun.
 
Onidajọ Ogunfowora ran agbẹjọro Apaniṣile leti wi pe ko ma ṣe gbagbe pe ẹẹmeji ọtọọtọ lo ti tọrọ iru aaye yii, ati pe oun ko ni i fun ni anfaani naa mọ, ko si gba pe eyi toun yoo gba gbẹyin ni tonii.
 
Bakan naa, nigba to n gba ẹnu onibara rẹ sọrọ, agbẹjọro Oloye Bamgboye, agbẹjọro Bayọ Ogungbemi ko awọn fọto ibi ti wọn ti bura, ati fọnran ibi ti wọn ti fi Oloye Bamgboye jẹ Oluwo silẹ fun ile-ẹjọ, to si ni awọn ẹlẹri wa nile ẹjọ lati sọrọ.
 
Idi oataki ree, ti Onidajọ Ogunfowora fi sọ pe ki Akinwande lọ tọwọ rẹ bọ aṣọ, ko si yee pe ara rẹ ni Oluwo ilu Ijẹja mọ.
 
Nigba toun funra rẹ n sọrọ lori idajọ naa, Oloye Arẹmu bamgboye sọ pe idunnu nla lo jẹ foun wi pe otitọ ti n farahan lakọtun, ati pe ile-ẹjọ ko raaye lati maa fi igba kan bo ọkan ninu, ti wón yoo si sọ otitọ bi ọrọ ba ṣe ri.
 
Bẹẹ lo sọ pe pẹlu nnkan to ṣẹlẹ lonii, o ti fi n han wi pe ibi rere ni idajọ naa yoo pada ja si, ti oun yoo si gbegba ọpẹ laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI