Anjọla, ọmọ Kọla Ọlawuyi ṣegbeyawo alarinrin l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Sunday, August 22, 2021

Anjọla, ọmọ Kọla Ọlawuyi ṣegbeyawo alarinrin l'Ekoo

Oni, ọjọ Abamẹta Satide, ọjọ kejilelogun lo pe ọsẹ kan gbako ti Anjọlaoluwa, ọmọ gbajugbaja sọrọsọrọ to doloogbe lọjọsi, Kọlawọle Ọlawuyi ṣe igbeyawo alarinrin pẹlu ololufẹ rẹ.
 
Satide, Abamẹta, ọjọ kẹrinla, oṣu yii ni ayẹyẹ igbeyawo naa waye ninu ṣọọṣi ridiimu, iyen The Redeemed Christian Church of God, ẹka ti Grace City to wa ni Somide Odujinrin Avenue, nitosi banki Polaris, Omole Phase 2, loju ọna Olowora, l'Ekoo.

Ọlamide lorukọ ololufẹ ti Anjọla fẹ, gẹgẹ ba a ṣe gbọ.
 
Gbọgan ayẹyẹ Marcelina Place, to wa ladugbo Isaac John, nitosi Radisson Blu, Ikeja GRA ni wẹjẹwẹmu ti waye.
Diẹ ree lara awọn fọto bi ayẹyẹ naa ṣe lọ.
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI