Awọn agbebọn kan niroyin ti fi to wa leti bayii wi pe wọn ti ji iya atọmọ rẹ gbe salọ, lẹyin ti wọn pa ọkọ rẹ, to tun jẹ baba ọmọ ti wọn ji gbe.
Oju ọna Ewu-Ayetoro Ekiti, nipinlẹ Ekiti la gbọ pe awọn agbebọn naa ti ṣọṣẹ buruku yii lọjọ Abamẹta, Satide, osẹ to ṣẹṣẹ kọja yii, gẹgẹ ba a ṣe gbọ.
Alukoro awọn ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lonii, ọjọ Aje, Mọnde, to si lawọn ti bẹrẹ iwadii lati ri awọn eeyan naa gba silẹ kuro lọwọ awọn to ji wọn gbe.
Siwaju si i la gbọ pe aadọta miliọnu naira lawọn ajinigbe naa n beere bayii, ki wọn to le fi iya atọmọ rẹ silẹ lahamọ wọn.
Abutu sọ pe iwadii awọn ti tu aṣiri ẹnikan to jẹ agbodegba fawọn ajinigbe ọhun, ẹni to pe orukọ rẹ ni Akinọla Fẹmi.
O lawọn ṣi n fọrọ wa a lẹnu wo lọwọ lati mọ ibi ti wọn ji awọn eeyan naa gbe salọ, ki wọn le ri wọn gba jade lai farapa.
No comments:
Post a Comment